Vivian Omeh: Iba Oluyole ní wọn kò jẹ́ kí obìnrin náà wo dígí títí tó fi pé ọmọ ọdún mẹ́jọ torí ilà ojú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Alhaji Nureni Akanbi
Yoruba ni ọna lo jin, ẹru ni baba nitori ko si ẹni to jabọ sile aye lati ọrun, ipasẹ eeyan kan la tọ wa.
Idi ree ti Iba Oluyole, tii se baale ile agboole naa, Alhaji Nureni Aknbi fi tẹwọgba ọmọbinrin kan, Vivian Umeh, tii gbe ilẹ Igbo dagba.
Gẹgẹ ba se mu iroyin naa wa fun yin saaju, ẹya Igbo ni iya orekelẹwa obinrin naa, to si gbe salọ silu wọn lati kekere, amọ baba Vivian, tii se sọja ti kọ ni ila agboole wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
- Ẹ́ ràgà bo ìṣọ̀kan Nàíjíríà, ìyàpà le mú ìṣẹ́ àwọn akọni wa já sásán - Osinbajo
- Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú
- Kí ló ń pa ẹbí Orisabunmi lọkọ́ọ̀kàn, àkúfà ni àbí àmúwá Ọlọ́run?
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
- Enugu ni mo ti wa, mò ń wá bàbá mí n‘Ibadan, mà á pa ara mi tí ń kò bá ri- Vivian Omeh
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- Wo àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tí àrùn Coronavirus gbẹ̀mí wọn
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Alhaji Akanbi ni Vivian ko gbọ ede Yoruba rara amọ o le sọ ede Igbo loju oorun, ọpẹ ila ti wọn kọ si loju nikan lo fi han pe Yoruba ni.

Oríṣun àwòrán, Alhaji Nureni Akanbi
O ni Vivian salaye pe kekere ni oun wa, ti iya oun ti ku, ti wọn ko si jẹ ki oun wo digi rara nitori wọn ni oun yoo ku ti oun ba wo digi.
"Vivian ni amọ nigba ti oun pe ọmọ ọdun mẹjọ ni oun dọgbọn wo oju ara oun ninu digi ni kọrọ, ti oun si wa ri ila ti wọn kọ si oun ni ẹẹkẹ, eyi ti ko sẹni to kọ iru rẹ laarin awọn to sun mọ oun."
Akanbi ni ọmọbinrin naa dunkooko lati pa ara rẹ ni ọjọ to kẹyin osu kejila ọdun to kọja, tii se ọjọ ibi rẹ, o ni ayafi ti oun ba mọ awọn ẹbi oun nikan ni oun ko fi ni se bẹẹ.
"Idi ree ti mo se ni mo ti gbaa bii ọmọ bibi inu mi nitori n ko fẹ ko pa ara rẹ. Ila wa loju rẹ, to si ni Ibadan ni wọn bi oun si, ọmọ ilu Ibadan naa si ni baba oun.
Mo ti pe awọn ẹbi mi, mo si sọ fun wọn pe mo ti tẹwọgba ọmọ naa bii ọmọ, to si ti fara mọ pẹlu, oun naa si tẹwọ gba mi bii baba rẹ.
Koda, o ti n jẹ orukọ mi, mo si n pe ni Fatimo gẹgẹ bi orukọ ti baba rẹ sọ, mo si ra irẹsi ati adiẹ fun pẹlu owo nla lati lọ fi se ọjọ ibi rẹ, ko si lọ se ajọyọ pe oun ti ni baba ati ẹbi tuntun."
Alhaji Nureni Akanbi tẹsiwaju pe ọmọbinrin naa ni ninu iwadi oun ni wọn ti sọ fun oun pe Balogun ni orukọ baba oun, amọ wọn ko ri akọsilẹ mọ nipa agboole to ti wa abi aworan rẹ.
O fikun pe oun ti lọ kede Vivian fun awọn akọroyin ko le rọrun lati tete ri baba rẹ.
Iba Oluyole ni ọpọ awọn eeyan to jẹ abọde sọja ti wọn bimọ silẹ Igbo atawọn ẹbi wọn lo ti n wa, to fi mọ awọn ẹbi to n jẹ Balogun, gbogbo wọn ni fọto Vivian ti wọn ri ko jọ ọmọ ti wọn n wa.
Amọ o ni iyalẹnu lo jẹ pe Vivian gan ti faake kọri pe oun ko wa baba kankan kiri mọ nitori oun ti mọ oun ni baba, oun si ti lọ gbadura si, ẹnikẹni ko si le gba oun lọwọ Alhaji Akanbi.
Enugu ni mo ti wa, mò ń wá bàbá mí n'Ibadan, mà á pa ara mi tí ń kò bá ri- Vivian Omeh

Adúgbò Ọjà‘ba nílùú Ibadan gba àlejò tí wọn kò gbà rí rí lọ́jọ́ kọkànlọ́dínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2021 nígbà ti kẹ̀kẹ̀ márúwá gbé ọmọbìnrin kan dé síbẹ̀.
Ọmọbìnrin náà púpa, ó sì gà, ó jẹ́ obinrin to jẹ ojú ní gbèsè nitori arẹwa ni.
Sùgbọ́n ó, kí ni kan ló ba àjàó jẹ́, apá rẹ̀ gun ju itan lọ, Bí ọmọnìnrin yìí ṣe rẹwà tó, kò rí ọkùnrin kankan fi ṣe adé-orí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- Wo àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì tí àrùn Coronavirus gbẹ̀mí wọn
- Kí ló ń pa ẹbí Orisabunmi lọkọ́ọ̀kàn, àkúfà ni àbí àmúwá Ọlọ́run?
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
- Buhari, pa ìtìjú mọ́ra láti sanwó fáwọn ajaguntà tí yóò kojú Boko Haram - Soyinka
- Sójà àti awakọ̀ fìjà pẹ́ẹ́ta nítorí ọgọ́rùn náírà, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sòfò
- Agbẹjọ́rò àgbà ní Nàìjíríà ti pàsẹ kí wọ́n dáwọ́ ètò ìgbanisíṣẹ́ NDLEA dúró
- Njẹ́ o mọ̀ pé àṣírí rẹ kò bò mọ́ lórí Whatsapp nítorí ìlànà tuntun tí wọ́n gbé síta?
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọmọbìnrin náà tó pé ara rẹ̀ ni Vivian Omeh ni ọ̀rọ̀ yìí gán ló fa a, tí òun fi bá ẹsẹ̀ òun sọ̀rọ̀ láti ìlú Enugu wa si ìlú Ibadan, lati mọ bàbà tó bi òun lọ́mọ.
Kíni ìdí tó fi ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ mọ bàbá rẹ̀ lásìkò yìí?
Gẹ́gẹ́ bi Vivian ṣe sọ, ó pẹ́ kí òun tó mọ pé, ilà tí ó wa ni ẹ̀kẹ́ òun le dá wàhálà sí òun lágbada lọ́ja iwájú.
Ó ní nígbà tí àsìkò tó láti ni ọkọ, gbogbo àwọn tó n kẹnu ifẹ́ sí òun ń bèrè pé, ṣe Yoruba ni òun ni àbí Igbo.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ìyá òun gbé òun sálọ sí ìlú Enugu nígbà ti òun wà ní kékere, kí bàbá òun má báa rí òun mọ́, sùgbọn wọ́n ti kọ ilà Oyo fún òun.
O ní títí ìyá òun oun fi kú, ǹkan tí ó kan sọ ni pé, ológun ni bàbá òun àti pé Balogun lo n jẹ́.
Ó ni nígbà tí àwọn ọmọ Igbo bẹ̀rẹ̀ si ni bèrè ìbéèrè pé, ṣe Igbo ni òun ni tàbi Yoruba, ní òun tún ni bóya kí òun máa fẹ́ Yoruba.
"Orí kọ̀ ọ̀ náà ní, àwọn ọmọ Yorùbá náà tún ni, dandan ní òun gbọ̀dọ̀ mọ ẹyẹ tó sun òun ni ìpínlẹ̀ Oyo, nítori àwọn kò lè fẹ́ obinrin to see se ko jẹ ẹbí àwọn.
Eyi ló mu mi gbéra lọ sí àgbàlá Iba Olúyọlé lati lọ mọ orísún bàbá mi."

Oríṣun àwòrán, Iba Oluyole
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, àrole Iba Oluyọle Alhaji Nureni Akanbi ní nígbà ti òun gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó ká òun lára nítorí ọ̀rọ̀ ti obinrin naa sọ.
"O ní tí òun kò bá mọ bàbá òun, òun yóò pa ara òun ki ọdún tó parí, ìyẹn ọjọ́ kọkanlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, tó tún jẹ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀.
Iba Oluyole ni òun ṣetan láti gba a gẹ́gẹ́ bi ọmọ, títí di ìgbà tí bàbá rẹ̀ rẹ yoo fi di mimọ.
"Mo fẹ́ gba ọ gẹ́gẹ́ bi ọmọ mí títí di ìgbà ti wọ́n yóò fi ri bàbá rẹ̀, mo ti kan sí agbẹjọ́rò mí, gbogbo ẹni to ba si fẹ́ gbà á, kí wọ́n kan sí mi"
Iwadii si n lọ lọwọ lori agboole ti baba Vivian ti wa ati boya o wa laye abi o ti jẹ Ọlọrun nipe ni.
Bi gbogbo ọrọ ba si se ri, BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.

















