Osun APC: Sẹ́nétọ̀, ọlọ́pàá Osun tako'ra wọn lórí wàhálà tó fẹ́ gbẹ̀mí sẹ́nétọ̀

Adelere Oriolowo ati Ileesẹ ọlọpa

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Adelere Oriolowo/PoliceNG

Gẹgẹbi iroyin abẹle ṣe sọ, awọn janduku atawọn eeyan kan ti wọn fura si gẹgẹ bi agbebọn, ya bo ibudo ipade ẹgbẹ APC nilu Ikire, ti wọn si kọlu ṣẹnetọ to n ṣoju ẹkun naa nile aṣofin agba, Sẹneto Adelere Oriolowo.

Ọn alati tanna wadi bi isẹlẹ naa se waye lo mu ki BBC Yoruba kan si Sẹnatọ Oriolowo ati ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Osun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ iyalẹnu lo jẹ pe Sẹ́nétọ̀ Oriolowo ati Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun tako'ra wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù naa.

Alaye ileesẹ ọlọpaa ree lori rogbodiyan APC:

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ni kii ṣe otitọ ni ahesọ iroyin to n lọ kaakiri pe awọn agbebọn lo kọlu Sẹnetọ Oriolowo.

Arabinrin Yẹmisi Ọpalọla, to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye fun BBC Yoruba pe, ileewe girama Ayedaade Grammar School ni ilu Ikire lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti n ṣe ipade.

Ibẹ lo ni awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ APC to wa nibi ipade naa, ti fi ẹsun kan Sẹnetọ Oriolowo pe ko ṣe awọn ohun to yẹ si ẹkun idibo rẹ, eleyi to mu ki o binu fi ipade naa silẹ.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Opalola ni ko si ẹnikẹni to fi ọrọ ipade naa to awọn ọlọpaa leti, nibi ti "wahala" naa ti bẹ silẹ.

Koda, igbakeji gomina ipinlẹ Ọsun, gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, wa nibi ipade naa.

Oriolowo salaye bi ikọlu naa se waye:

Amọṣa ninu ọrọ tirẹ, Sẹnetọ Oriolowo ṣalaye fun BBC Yoruba pe, alaafia ni oun n wa nibi ipade naa, ki o to di pe awọn janduku ṣadede yọ si oun.

"Wọn ran awọn to kọlu mi ni, wọn si ti ṣe eto ikọlu yii daadaa" ni ọrọ ti Sẹnetọ Oriolowo sọ.

Nibo ni ọrọ naa de duro bayii?

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si ẹni lee sọ ni pato awọn to wa nidi ikọlu naa.

Awọn onwoye kan sọ pe ikọlu naa ko ṣẹyin wahala abẹnu to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu naa, paapaa julọ, laarin awọn ololufẹ gomina ana ni ipinlẹ naa, Rauf Arẹgbẹṣọla ati gomina to wa nipo lọwọ, Gboyega Oyetọla.

Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú

Osun APC: Ori kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́wọ́ Àìkú

Oríṣun àwòrán, orilowo

Saaju la ti sọ fun yin pe Sẹ́natọ tó n sojú ẹkùn ìwọ̀-oorùn ìpínlẹ̀ Osun nilé ìgbìmọ̀ asofin àgbà nilùú Abuja Aderele Orilowo bọ́yọ lọ́wọ́ ikú òjijì lọ́jọ́ àìkú.

Ìròyìn sọ pé ń ṣe ìpàdé ẹkùn rẹ̀ nílé ẹgbẹ́ nílùú Ikire nígbà tí àwọn jàgùdà yawọ olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Irewole ìpínlẹ̀ Osun pẹ̀lú àdá àti kùùmọ̀.

Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀sọ ààbò tó sọ sẹ́natọ náà ti kò gbà àwọn jàndùkú náà láàyè láti kojú sẹnatọr ti ti ti wọ́n fi gbé sálọ

Osun APC: Ori kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́wọ́ Àìkú

Oríṣun àwòrán, Aderele orilowo/facebook

Kò tán síbẹ̀, nígbà ti tí sẹ́natọ̀ náà móríbọ́, ni àwọn jàndùkú náà kó sdi àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ku níbi ìpàdé òun.

Bákan náà ni sẹnatọ òun kọ sí ojú òpó facebook rẹ̀ pé, orí ko òun yọ lọ́wọ́ àwọn agbanipa, ogo ni fun Ọlọ́run

Osun APC: Ori kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́wọ́ Àìkú

Oríṣun àwòrán, orilowo

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, akọwé sẹ́nátọ̀ ọ̀gbẹ́ni Niyi Isamotu sàlàyé pé, àwọn kò ṣẹ̀ṣl maa ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ APC ni ilú Ikirie.

O ní bótilẹ̀ jẹ́ pé, ko sí ẹni tó farapa, síbẹ̀ gbogbo mótò tó wà ní àyíkà ni wọ́n bàjẹ́ pátá. "Ní kété tí a debẹ̀ ni a ri pé, wàhálà bẹ̀rẹ̀, sùgban pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀sọ́ àbò, ni wan sáre gbé sẹ́natọ̀ sálọ kúrò níbẹ̀

Osun APC: Ori kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́wọ́ Àìkú

Oríṣun àwòrán, Aderele orilowo/facebook