Orisabunmi: Àbúrò èèkàn òṣèré Orisabunmi tó jáde láyé ní ọjọ́ méjì péré ló lò níléèwòsàn kí ikú tó dé

Oríṣun àwòrán, Tundeolayusuf/instagram
Awọn iroyin tuntun tun jade nipa iku oloogbe Fọlakẹ Arẹmu ti ọpọ mọ si Oriṣabunmi, eekan oṣere tiata ati sinima lorilẹede Naijiria to jade laye ni ọjs diẹ sẹyin.
Ọjọ meji ni aisan to ṣe Oriṣabunmi fi ṣe, gẹgẹ bi aburo rẹ, iyaafin Toyin Akinoso ṣe ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan.
Ni kete ti aisan naa bẹrẹ lo si lọ si ileewosan nibi to dakẹ si.
Iyaafin Akinoso to jẹ aburo oloogbe naa ni awọn jumọ ṣere lati ọjọ kejila oṣu kejila ọdun 2020 titi di ọjọ kini ọdun 2021.
O ni iba lasan lo ṣe Oloogbe Oriṣabunmi to fi lọ si ileewosan nibi ti o ti jade laye.
O niiku to ṣe gbogbo ẹbi ni kayefi ni iku Oriṣabunmi.
"Ohun ti inu mi kan dun si ni pe bi o ṣe lo ile aye rẹ."
O ni eeyan nla ni Ọlọrun gba lọwọ ẹbi naa ati pe Ọlọrun nikan lo lee di aye to fi silẹ.
O ni ọrọ to sọ fun oun ni ọjọ kini ọdun 2021 ni pe ki awọn maa gba adura.
O ni o tẹẹ mọ oun leti pe ki awọn maa dupẹ ni nitori pe wọn ko duro ibanujẹ lori ẹnikẹni ninu ẹbi naa laimọ pe yoo jade laye laipẹ.













