Orisabunmi : Afeez Ọwọ ṣàlàyé ìdí tó fí padà yọ àwòrán Orisabunmi kúrò lójú òpó rẹ̀
Ni idahun si ariwo tawọn eeyan n pa lori oju opo rẹ, gbajugbaja oṣere sinima Yoruba, Afeez Ọwọ ti yọ aworan ikede oku Orisabunmi kuro loju opo Instagram rẹ.
Igbesẹ yi to fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ BBC Yoruba lo sọ pe oun ṣe gbe lẹyin ti oun ri pe awọn eeyan faraya lori aworan naa.
Afeez Ọwọ tun bọ ṣalaye pe oun naa mu aworan yi loju opo mii ni ti awọn oṣere miran naa si tun ti mu lọdọ oun.
O ni o jẹ iyalẹnu fun oun pe awọn eeyan bẹrẹ si ni gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti lai beere ibi toun ti ri aworan naa.
''Ṣebi ẹyin naa ni BBC ti fi mi kọ akọle lai wadi ọrọ lọwọ mi?Ta lẹni to ni oun sọ fun mi pe kin yọ aworan naa? Nigba wo lo pe mi?''
BBC Yoruba wa salaye fun pe awọn kan si lori ago rẹ lati fesi si ọrọ naa ṣugbọn o ti pa foonu rẹ nigba taa fi pe e.
Yatọ si eyi, Ọwọ ti yọ aworan naa kuro loju opo rẹ ti ko si ni rọrun lati ri ibi tawọn eeyan ti ṣalaye fun pe ki o yọ kuro.
Bakan naa, Afeez Ọwọ ko ṣọ pato ibi to ti mu aworan yi bẹẹ si ni ko tọrọ aforijin pe oun lo aworan naa eyi to ṣafihan Orisabunmi ninu posi botilẹjẹ wi pe ọtọ lẹni to lo aworan rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFEEZ OWO/ORISABUNMI
'Òkú Orisabunmi' dá wàhálà sí 'Afeez Ọwọ' lọ́rùn
Mọlẹbi arabinrin kan to ku ni Amẹrika ti Afeez Owo fi aworan rẹ pe ti Orisabunmi ti kesi osere tiata naa ko yọ aworan naa kuro loju opo rẹ.
Afeez Ọwọ fi aworan yi sita soju opo rẹ nipa iku Oriṣabunmi eyi to fi n fa awuyewuye debi pe awọn kan to fi mọ mọlẹbi obinrin to lo aworan rẹ ti n bẹnu atẹ lu.
Lasiko ti awọn eeyan n ṣe idaro iku gbajugbaja oṣerebinrin ere tiata Yoruba nii, Orisabunmi,orisirisi ọna lawọn eeyan fi n kẹdun iku rẹ.
Ṣugbọn ibanikẹdun eleyi ti Afeez Owo ṣe yi ti mu ibinu wa ati ọrọ kobakungbe lati ọdọ awọn eeyan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Aworan taa n wi yi ṣafihan Orisabunmi nigba to wa laye ati aworan ẹnikan to wa ninu posi ti kii ṣe Orisabunmi.
Mọlẹbi arabinrin ti o wa ninu posi yi ti BBC Yoruba ba sọrọ, Olorunmodimu Nike Ebunoluwapo jẹ olutaja lori opo Instagram @ike_store_epitome_of_fashion.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo o sọ fun BBC Yoruba pe ohun ti kesi Afeez Owo lati yọ aworan mọlẹbi oun kuro loju opo rẹ ṣugbọn o keti ikun si ipe yi.
Afeez Ọwọ kọ si oju opo rẹ ni Instagram lori aworan yi pe ki eledua tẹ Oriṣabunmi ṣafẹfẹ rere.

Oríṣun àwòrán, AFEEZ OWO
Lootọ lo jọ pe o n ba awọn eeyan kẹdun iku Orisabunmi ṣugbọn aworan to fi gbe idaro rẹ lẹyin gaan kii ṣe ti Oriṣabunmi.
Pupọ awọn to wa si oju opo rẹ mi ni iwa aibọwọ fun ẹni to lọ ni Afeez Owo hu pẹlu aworan yi.
BBC Yoruba gbiyanju lati pe Afeez Owo lori ẹrọ alagbeka rẹ ṣugbọn nọmba rẹ ko lọ.
- Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham
- Ó ti tó àsìkò kí Nollywood fòpin sí èré ilé babaláwo lílọ - Clarion Chukwura
- Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
Titi di igba ta fi n ṣe akojọpọ iroyin yi, Afeez Owo ko ti yọ aworan yi kuro loju opo rẹ.













