Èèyàn kan kú, ẹni mẹ́ta farapa nínú àkàsọ̀ ìgbàlódé(lift) tó já ní Cocoa House n'Ibadan

Cocoa House ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ile isẹ Odu'a Investment Company Limited ni nkan bi aago mọkanla owurọ oni ni awọn osisẹ to n mojuto atunse akasọ igbalode fun igbokegbodo to yanranti lenu iṣẹ ni wahala dede ṣẹyọ ti akasọ naa si ja lọlẹ.

Ninu atẹjade ti adari igbokegbodo ile isẹ Victor Ayetoro fọwọsi lo ti salaye pe akasọ naa kuna ti ọkọ to n gbe eniyan lọ soke sodo si ja lulẹ.

O ni o ṣe ni laanu pẹ okan ninu awọn osiṣẹ to n sisẹ nibẹ ba iṣẹlẹ nla ibi naa rin.

Awọn osisẹ to ku ninu rẹ farapa diẹ ti wọn si ti n gba itọju nile iwosan.

Oludari ile iṣẹ naa ti gbọ si iṣẹlẹ naa ti awọn asoju wọn si ti de lati mojuto iṣẹlẹ ọhun, bakan naa ni wọn ti fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.

Atẹjade naa fi kun pe ile iṣẹ ba ẹbi oloogbe oun kẹdun o si bẹ eedua ko fun wọn ni opre ofẹ lati bori iṣẹlẹ ajalu yii