Alleged Sexual harassment: Ẹ̀gbọ́n baba Barakat ṣàlàyé bó ti gbé e lọ sílé kọmísọ́nà Ogun tí wọ́n ní kó lọ rọ́kún ńlé

Saheed lasisi ati Abiodun Abudu-balogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abiodun Abudu-Balogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi o tilẹ jẹ pe ọgbẹni Adesola Melojuekun to jẹ baba ọmẹdebinrin Barakat Melojuekun to fẹsun iyọnilẹnu fun ibalopọ kan Kọmisana fọrọ ayika nipinlẹ Ogun, Abiodun Abudu-Balogun ni oun ko nifẹ lati ṣe ẹjọ, awuyewuye ko tii tan an lori ọrọ naa.

Ọgbẹni Lasisi Saheed to jẹ ẹgbọn baba Barakat ti ṣalaye bi ohun ti ṣe gbe ọmọdebinrin ọdun mẹrindinlogun naa lọ sile Họnarebu Abudu-Balogun.

Ọgbẹni Saheed fidi rẹ mulẹ pe lootọọ loun gbe ọmọ aburo oun lọ sile kọmiṣọnna ọrọ ayika, amọ oun ko mọ nkan to ṣẹlẹ ninu ile laarin Barakat ati Abudu-Balogun.

Ninu fidio kan to fi sori ayelujara, Saheed ṣalaye pe Barakat tẹle kọmiṣọnna naa lọ sinu yara kan lẹyin ti oun mu de bẹ tan.

''Awọn mejeeji si tun jọ jade sita pada lẹyin bi iṣẹju mẹwaa ti wọn jọ wọle lọ, mi o mọ ohun kan ju bayẹn lọ,'' Saheed lo ṣalaye bẹẹ.

Saheed ni ''lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2020 ni a ṣe ipade kan nile kọmiṣọnna ọrọ ayika ipinlẹ Ogun nibi to ti sọ pe oun nilo ẹni to ba mọ nipa lilo ẹrọ kọmputa, eleyi ti mo sọ fun un pe mo mọ ọmọdebinrin kan to mọ nipa lilo ẹrọ kọmputa daadaa.''

''Wọn ni ki n mu ọmọ naa wa, lẹyin naa ni mo lọ ṣalaye fun Barakat ti mo fi si gbe e lọ sile kọmiṣọnna ọhun,'' Saheed ṣalaye.

Lẹyin ti baba Barakat ati oun gan an ti pohun da pe awọn o ṣejọ mọ lori ọrọ naa, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to n ri si iṣẹ iwadii ẹsun ọdaran ti sọ pe ohun yoo tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ naa.

Kí ló mú kí Baba Barakat tó fẹ̀sùn ìyọnilẹ́nu torí ìbálòpọ̀ kan kọmísọ́nà àyíká ìpínlẹ̀ Ogun pàlù ẹnu dà?

Ọrọ ti n gbọna mi yọ lori awuyewuye laarin Kọmisana fọrọ ayika nipinlẹ Ogun ati mọlẹbi ọmọdebinrin kan to fẹsun kan an pe o n yọ ọmọ naa lẹnu lori ibalopọ.

Idi ni pe baba ati ọmọ naa, Adesola Melojuekun ti ṣe fọnran fidio mi sita nibi ti o ti ni awọn ko lẹjọ ro pẹlu Kọmisana Abiodun Abudu-Balogun mọ.

Aworan Baba Barakat ati Kọmisana

Oríṣun àwòrán, BBC

Ninu fọnran ti baba Barakat fi sita yi , o ni ede aiyede lo waye laarin Barakat ati Kọmisana Abiodun.

Baba Barakat nikan kọ lo gbe fidio sita.

Barakat naa fi fidio sita laipẹ si igba ti wọn ni ki kọmisana lọ rọọkun nile.

Baba Barakat ninu fidio taa ri sọ pe ''Aigbọraẹni ye kan waye laarin Kọmisana ati ọmọ mi,lẹyin ti a si ti ti ri bayi, mo ro pe o yẹ ki n fi to araalu ati awọn eeyan ilẹ okere leti pe ki a jẹ ki ọrọ yi tan sibẹ''

O tẹsiwaju pe ''Mi o ṣẹjọ mọ , mo si fẹ ki ẹ ṣalatilẹyin mi lori ipinu mi yi bi ẹ ti ṣe ṣe fun mi ṣaaju nibẹrẹ ọrọ yi.''

BBC ko ti ribi fidi ododo fidio yi rinlẹ yala lati ọdọ baba tabi ọmọ ti ọrọ yi kan.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Nigba taa kan si alukoro ọlọpaa Ogun,Abimbola Oyemyemi ti ijọba ni ki wọn ṣe iwadii ọrọ naa, niṣe lo kọ lati gbe ago rẹ.

Amọ ṣa ninu fọnran fidio yi, Baba Barakat ko sọ boya kọmisana tọrọ aforijin bẹẹ naa ni ko tọrọ aforijin lọdo Kọmisana lori pe o ba orukọ rẹ jẹ.

Ìjọba ní kí kọmíṣọ́nnà àyíká ìpínlẹ̀ Ogun lọ rọ́kún ńlé lórí ẹ̀sùn ìyọnilẹ́nu torí ìbálòpọ̀

Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni Ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe ki kọmiṣọna fun ọrọ ayika, Họnarebu Abiodun Abudu-Balogun lọ rọkun nle lẹyin ti wọn fẹsun iwa ipa ibalopọ kan an pẹlu ọmọdebinrin.

Ijọba sọ ninu atẹjade kan ti akọwe ijọba ipinlẹ, Ọgbẹni Tokunbo Talabi fi sita lọjọ Aiku pe igbesẹ ijọba yii yoo wa sibẹ titi di asiko ti iwadii lori ọrọ naa yoo fi pari.

Barakat Melojuekun to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni wọn fẹsun kan Abudu-Balogun pe o n yọ lẹnu fun ibalopọ.

Kọmiṣọnna naa fun ra ti kọkọ fi atẹjade kan sita pe oun ko mọwọ mẹsẹ lori ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ṣugbọn ijọba ṣalaye pe oun ko ni ṣegbe lẹyin ẹnikan lo jẹ ki oun sọ fun kọmiṣọnna tọrọ kan lati dawọ iṣẹ duro naa fun igba.

Ijọba Ogun sọ ninu atẹjade to fi sita pe ohun yoo ri wi pe ohun fidi ododo mulẹ lori ọrọ naa.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ogun ti paṣẹ fun kọmiṣọnna ọrọ ayika lati jọwọ gbogbo ohun to wa lọwọ rẹ fun akọwe agba ẹka ijọba to n ri si ọrọ ayika.