Akure Lady Suicide: A kò ní ṣe ìwádìí kankan lórí òṣìṣẹ́ Shoprite tí wọ́n ló gba ẹ̀mí ara rẹ̀ nílùú Akure-Ọlọ́páà

Okun ti wọn fi n pokunso

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti fesi si ọrọ iku arabinrin kan ti wọn sọ pe o gbẹmi ara rẹ ni Akure.

Alukoro ọlọpaa Ondo Tee-Leo Ikoro ṣalaye fun BBC pe ''ẹni to ba gbẹmi ara rẹ, ko si iwadi kankan taa le ṣe , ẹni ti ku ti ku ''.

Ikoro ni lootọ ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ṣugbọn awọn ko lọ sibẹ lati lọ wo nitori iṣẹlẹ igbẹmi ara ẹni kii ṣe ohun tawọn tun le ṣe iwadi le lori.

''Nkan kekere ni, ko si ẹsẹ kankan ti eeyan ba gbẹmi ara rẹ.Paapa julọ nigba ti ẹnikankan ko ba fi ọrọ yi to ọlọpaa leti''

O ni Ọlọpaa kii ṣadede ṣe iwadii ẹsun pe eeyan gbẹmi ara rẹ ayafi ti ẹni naa ba gbiyanju ti ko ri ara rẹ pa,.

''Nigba naa lo to wa di ẹsẹ pe o fẹ gbẹmi ti ko lẹtọ lati gba.Bi bẹ kọ, bo ba ku , ko si nkankan taa le ṣe si''

Yatọ si eyi, Ikoro sọ pe ohun ko ro wi pe o gbẹmi ara rẹ ni.

Iroyin iku arabinrin yi jẹ eleyi ti awọn eeyan Akure ti n ṣeemọ si lati igba to deti igbọ awọn eeyan.

Laisun ọjọ ọdun tuntun ni wọn ba oku Jumoke Kehinde ninu iyara rẹ ladugbo Kajola,opopona Oda ni Akure.

Ẹni ọdun mẹtalelogun naa ti wọn lo jẹ oṣiṣẹ ile itaja Shoprite la gbọ pe wọn da duro lẹnu iṣẹ lọjọ taa n wi yi.

Àkọlé fídíò, Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

BBC gbiyanju lati ba oludari ile itaja Shoprite naa kan sọrọ ṣugbọn o ni oun ko bawọn ṣiṣẹ mọ nitori naa oun ko ni le dahun si ibeere wa.

Ko ti si aridaju boya lootọ lo mu ogun sniper tawọn kan sọ pe o ṣokunfa iku rẹ.

Nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa naa ti ṣe sọ pe awọn ko wulẹ lọ sibẹ lọ ṣe iwadii, ko si ẹni to le sọ pato iru iku to pa Jumoke.

A n gbiyanju lati ba awọn mọlẹbi Jumoke sọrọ.

Ni kete ti a ba ri wọn kan si la o mu alaye wa lati ọdọ wọn nipa ohun to le faa ki Jumoke gbẹmi ara rẹ to ba ṣe pe lootọ ni pe o ṣe bẹ.