Amotekun: Olórí ikọ̀ Amotekun l’Oyo ní àwọn ọ̀tá ìtẹ̀síwájú ń sa ipá láti ba ikọ̀ Amotekun lórúkọ jẹ́

Oríṣun àwòrán, Twitter/oyo state government
Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju ti ṣe alaye wi pe awọn eeyan kan ti inu wọn ko dun si idasilẹ ikọ naa lo n sa ipa wọn lati ta ẹrẹ ba aṣọ ala ikọ eto aabo abẹnu ti ijọba fi lọlẹ.
Ninu ọrọ to ba akọroyin BBC Yoruba sọ l'ọjọ Iṣẹgun, Ọlayanju ni lara awọn ohun elo awọn abanilorukọ jẹ naa ni iroyin ofege ti wọn gbe kaakiri.
- Èèmọ̀ wọ̀lú, Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ gbé ọmọ ọ̀gá rẹ̀ àti káàdì ìgbowó ATM sálọ l'Ondo!
- Arábìnrin òṣìṣẹ́ 'Shoprite' tí wọ́n lò gbẹ̀mí ara rẹ̀ , àlàyé rèé láti ẹnu ọlọ́pàá
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé-Elebuibon
- Ìpínlẹ̀ Eko yí ohùn padà, Ó kéde ọjọ́ tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Ọlọ́pàá Oyo n wa afurasí tó ṣekú pa oníṣòwò àti ọmọ ọdún mẹ́sán án méjì ní Ibarapa
O tẹsiwaju wi pe iwa ọdaran to le ni ogoji ni ikọ Amọtẹkun ti dẹkun rẹ laarin oṣu mẹfa ti ikọ naa bẹrẹ iṣẹ, bẹẹ sini eeyan mẹji ọtọọtọ ni ikọ naa ti ran lọ atimọle nipasẹ ijọba, ṣugbọn dipọ ki awọn eeyan kan ki ikọ naa kuuṣẹ, gbogbo ọna ti ijọba yoo fi kabamọ lori idasilẹ ikọ Amọtẹkun ni wọn n wa kiri.
Bakan naa ni Ọlayanju tan imọlẹ si awuyewuye to n waye lori ẹsun ti wọn fi kan Amọtẹkun wi pe aṣoju ikọ naa yinbọn fun akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan kan ati oṣiṣẹ ọlọpaa kan laarin oṣu meji sira.
O ni lootọ ni Amọtẹkun ṣekupa ọkan lara awọn ọdaran to n yọ awon olugbe agbegbe Ọyọ lẹnu lọganjọ oru, ṣugbọn iṣẹlẹ naa ti waye ki wọn to fi idi ọrọ mulẹ wi pe akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan ni afurasi naa.
Lorii kọnstabu ọlọpaa ti iroyin sọ pe aṣoju ikọ Amọtẹkun kan yinbọn fun ni agbegbe Ọyọ bakan naa, Ọlayanju ṣalaye pe kii ṣe pe Ibrahim Ogundele, oṣiṣẹ ajọ Amọtẹkun naa ṣa dede ṣina ibọn bolẹ fun ọlọpaa naa, iyẹn Fatai Yẹkini ni itan.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko si idi fun Ibrahim lati ṣina ibọn fun Fatai nitori pe wọn ko ni ikunsinu, ija tabi ita ti ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Kodaa, o ni ọrẹ ni awọn mejeeji.
Ajagunfẹyinti Ọlayanju ṣalaye pe awọn ọlọpaa lo ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun lati wa kun wọn lọwọ tu oju agbo awọn eeyan kan to n ṣe ajọdun kanifa "Carnival" ọdun tuntun ni ilu Ọyọ lẹyin ti awọn ọẹọaa ti kọkọ kilọ fawọn agbodegba eto naa ṣaaju pe wọn ko gbọdọ ṣe ohun to jọọ.
O ni ibọn ọwọ Ogundele ṣa dede yin ni eyi ti oyinbo n pe ni "accidental discharge" ti o si ba ọlọpaa naa ni itan.
Ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn si ti gbe e lọ si ileewosan, ti oṣiṣẹ ọlọpaa naa si pada si ilẹ rẹ lẹyin ti o gba itọju tan laarin wakati mẹrinlelogun.
BBC Yoruba beere iru idanilẹkọ ti ikọ Amọtẹkun gba ki wọn to bẹrẹ iṣẹ ati ibi ti wọn ti ri nnkan ijagun wọn, ẹsi ti adari ikọ naa fọ ni wi pe awọn ologun ati ọlọpaa lo ṣe idanilẹkọ fun awọn aṣoju ikọ Amọtẹkun fun ọsẹ mẹta gbako nile ẹkọ giga kan to n ba nilu Ọyọ.
"Lara idanilẹkọ ti wọn si gba ni bi wọn ṣe le gba ibọn mu, bi wọn ṣe le ṣe ọfintoto ọrọ, bi wọn ṣe n hu iwa pẹlu ara ilu ati awọn ẹṣọ aabo mii".
Ṣugbọn Ọlayanju fi kun ọrọ rẹ pe ijọba kọ lo fun ikọ Amọtẹkun ni ibọn ati awọn nnkan ijagun ti wọn n lo.
O ni pupọ ninu awọn aṣoju ikọ naa lo ti fi igba kan jẹ ọdẹ tẹlẹri, ti wọn si ni awọn nnkan ijagun ti wọn n lo.
Adari ikọ Amọtẹkun fi ku ọrọ rẹ wi pe awọn eeyan kan wa ti wọn fẹ lati kopa ninu ikọ Amọtẹkun, ṣugbọn awọn ko fi aye gba wọn nitori ọwọ wọn ko mọ, eyii lo mu ki wọn gun le igbesẹ "bi adiyẹ ba da mi loogun nu, maa si fọọ lẹyin".
Òṣìṣẹ́ Amotekun kò mọ̀ọ́mọ̀ yìnbọn lu ọlọ́pàá l'Oyo, ìdí tó fi yìnbọn rèé -Olórí ikọ̀ Amotekun l'Oyo

Oríṣun àwòrán, Premium
Ni ọjọ Aje ni iroyin jade si igboro aye pe oṣiṣẹ ikọ alaabo Amọtẹkun kan ti yinbsn fun ọlọpaa kan ni ilu Ọyọ.
Nibayii, ikọ alaabo Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ ti ṣalaye lori bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.
Adari ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ṣalaye pe kii ṣe pe Ibrahim Ogundele, oṣiṣẹ ajọ Amọtẹkun naa ṣa dede ṣina ibọn bolẹ fun ọlọpaa naa, iyẹn Fatai Yẹkini ni itan.
- Ìpínlẹ̀ Eko yí ohùn padà, Ó kéde ọjọ́ tuntun fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé-Elebuibon
- Ọlọ́pàá Oyo n wa afurasí tó ṣekú pa oníṣòwò àti ọmọ ọdún mẹ́sán án méjì ní Ibarapa
- Nǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀gá Àgbà fásitì UNILAG tẹ́lẹ̀rí, Ibidapo Obe tó jáde láyé
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko si idi fun Ibrahim lati ṣina ibọn blẹ fun Fatai nitori pe wọn ko ni ikunsinu, ija tabi ita ti ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Ajagunfẹyinti Ọlayanju ṣalaye pe awọn ọlọpaa lo ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun lati wa kun wọn lọwọ tu oju agbo awọn eeyan kan to n ṣe ajọdun kanifa "Carnival" ọdun tuntun ni ilu Ọyọ lẹyin ti awọn ọẹọaa ti kọkọ kilọ fawọn agbodegba eto naa ṣaaju pe wọn ko gbọdọ ṣe ohun to jọọ.
O ni ibọn ọwọ Ogundele ṣa dede yin ni eyi ti oyinbo n pe ni "accidental discharge" ti o si baọlọpaa naa ni itan.
Ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn si ti gbe e lọ si ileewosan, ti awọn ọlọpaa si mu Ibrahim Ogundele to jẹ oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun naa timọle.
Ṣé lóòtọ́ ni òṣìṣẹ́ Amotekun kan yìnbọn fún ọlọ́pàá ní Oyo?
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ eleto abo tiwantiwa, iyẹn Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ibrahim Ogundele ti yinbọn si ọlọpaa kan ni ilu Ọyọ.
Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, ikọ Amọtẹkun ni agbegbe Isalẹ Ọyọ ni Sbẹni Ogundele wa pẹlu.
Bakan naa ni iroyin fi kun un pe Kọsitabu ni ọlọpaa ti wọn yinbọn si naa ni agọ ọlọpaa Ojongbodu ni ilu Ọyọ, orukọ rẹ a si maa jẹFatai Yẹkini.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ẹsẹ osi ni ọta ibọn naa ti baa ti wọn si ti gbe e lọ si ileewosan nla ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa lagbegbe Owode ni ilu Ọyọ.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ṣalaye pe lasiko ti awọn ọlọpaa lati agọ ọlọpaa Ojongbodu n gbiyanju ati tu awọn ọdọ kan to n gbaradi ati ṣe ajọdun ọlọdọọun wọn ti a mọ si Carnival ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.














