Gómínà ìpínlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu ní àdánù ńlá ni ikú Ogunbodede, amúgbálẹ́gbẹ́ rẹ̀ tó kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ wò

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti bẹ ẹbi oloogbe Tosin Ogunbọdede to jẹ adari eto fun ọfiisi rẹ, "Chief Protocol Officer" wo lati ba wọn kẹdun iku olori ẹbi naa.
Amofin Ogunbọdẹde padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ kan to waye lopopona marosẹ Ileṣa si Akurẹ lopin ọsẹ to kọja.
Gomina Akeredolu ṣe apejuwe iku amofin Ogunbọdẹde gẹgẹ bi adanu nla fun oun gẹgẹ bi ẹni kan ati fun ipinlẹ Ondo lapapọ.
O tọka si oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ṣeẹ fi ọkan tan to si ṣee gbẹmile.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ eniyan to mọ iṣẹ rẹ niṣẹ ni oloogbe Amofin Ogunbọdẹde nigba aye rẹ ko si fi ijafafa iṣẹ jafara rara.
Èmi gan ni mo pàdànù nípa ikú 'Chief Protocol mi' - Gomina Akeredolu
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ti pàdánu Tosin Ogunbodede to jẹ adari eto fun gómínà ìpińlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu.
Iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa waye ní òpópónà márosẹ̀ Ilesha si Akure, nigba ti Ogunbodede n bọ lati Ibadan to ti lọ ki ibatan rẹ̀.
Gómìnà ìpińlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu nínú àtẹjáde ti Kọ́mísọ́nà fún ètò ìròyìn àti ìlànilọ́yẹ̀ fọ́wọ́sí, sàlàye pé ìbánújẹ́ ńla lo jẹ́ láti pàdánù olórí ètò ilé ìjọba òun.
Gómìnà fí kun pé, òun gan ni òun pàdánù lórí ikú Ogunbodede, sùgbọ́n ó rọ gbogbo ènìyàn láti gbà pé àmúwá Ọlọ́run ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún pẹ̀lú kọ́mísọ̀nà náà sàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ ńla ibi náà wáye ni ǹkan bi aagọ mẹ́jọ kù ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógúnn ni alẹ Ọjọ Satide, ọjọ́ kejì, oṣù kíní ọdún 2021, lópópónà Ilesha-Akure.
Ìkú òjiji náà wáye lásìkò tó n ń bá láti ọdọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọjọgbọ́n Benjamin Ogunbodede tó ti ṣe àìsàn tipẹ̀ nílù Ibadan

Oríṣun àwòrán, OGUNBODEDE/FACEBOOK
"Chief Protocol" Tosin Ogunbodede tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Owo ní kọ́mísọnà ni wọ́n yóò gbé òkú rẹ̀ wọ ìlú lónìí, láti se gbogbo ètò tó yẹ lái fi falẹ̀.
Àti òun àti awakọ̀ rẹ̀, ni wọ́n jọ pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà ti ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Corolla wọ́n kó ṣenu ọkọ̀ àjàgbé
Ó ní ọkàn nínú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ni ''Chief of Protocol" Tosin Ogunbodede ti jẹ́ ọlọrún nípè, nígbà ti èni kejì wá ni ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọrun.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ondo Tee Leo Ikoro náà fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múll fún BBC Yoruba














