Muhammadu Buhari 2021 Broadcast: Ààrẹ ní àwọn ọ̀dọ́ yóò gbádùn àtìlẹyìn òun lọ́dún tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ba awọn eniyan orilẹ-ede naa sọrọ nipa ọdun tuntun, lọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2021.
Nkan akọkọ to sọ ni pe O dupẹ lọwọ Ọlọrun to sọ Naijiria ninu ọdun 2020, to si tun fun ni oore ọfẹ lati ri ọdun tuntun.
O ni ọdun 2020 ni ọdun to lagbara ju lati igba ti Naijiria ti wa gẹgẹ bi orilẹ-ede. Eyi ko ṣẹyin aarun Covid-19.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbogbo ọjọ́ kérésì ni ìyá Leah Sharibu ń sàìsàn, ó tún ti wà nílé ìwòsàn
- Gbàjarè! Ràkúnmí làwọn agbébọn ń lò láti gbé àdó ikú wọ òkè ọya - Arewa figbe ta
- Bí 2020 ṣe ń lọ sópin, Alapinni Oosa wúre ọdún fún ọmọ Yorùbá
- A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa - Mama Fasoyin
- Àkójọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dára àti èyí tó burú tó wáyé ní 2020
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàíjíríà tó jáde láyé lọ́dún 2020
- Wo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù fóónù tí Whatsapp kò ní bá ṣiṣẹ́ mọ́ lọ́dún 2021
- Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ
Bakan naa lo fikun ọrọ pe ijọba yoo ra abẹrẹ ajẹsara, ti yoo si pin kari gbogbo ẹkùn lai ṣe ojuṣaaju.
O ṣalaye pe ọdun 2020 yoo dan ẹmi ifarada ati okun rẹ wo gẹgẹ bi orilẹ-ede wo, boya o le la wahala kọja.
Amọ o jade ninu rẹ pẹlu ireti ọtun pe o le koju gbogbo iṣoro to ba koju wa lọdun 2021.
O ni ao gbọdọ ṣa i ma daro awọn eniyan wa ti ko ni iru anfaani bẹ ẹ.
"Naijiria yoo duro, yoo si ṣe aṣeyege."
Awọn koko ọrọ ti Buhari sọ gẹgẹ bi aṣeyọri ọdun 2020
Aarẹ mẹnuba pe nigba ti awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria jade sita lati ṣe iwọde ENDSARS, ijọba tẹti gbọ wọn.
Mo tun lo anfaani ọdun tuntun yi lati tun ẹjẹ jẹ fun awọn ọdọ to nilo iranlọwọ wa pe, didadaabo bo orilẹ-ede yii, lo le daabo bo ọjọ iwaju awọn iran to n bọ.
Afojusun ijọba yii ni lati ṣe nkan marun ti awọn ọdọ naa beere fun, nitori a ni oye pe didara Naijiria lo jẹ gbogbo wa logun."
Buhari sọ pe nigba ti gbogbo rogbodiyan naa bẹrẹ, oun jẹjẹ pe gbogbo nkan to ba gba ni oun yoo fun.
"A ti gbọ ohun yin, ao si tẹsiwaju lati maa tẹti si yin.,"
Lori ọrọ awọn ọdọ bakan naa, Aarẹ Buhari sọ pe oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn aṣofin lati pese ayika to dara fun wọn lati ṣamulo ọgbọn inu wọn, ti a le ṣe iranlọwọ fun, jakejado Naijria.
Eto aabo:
- Atunto ati riro awọn ileeṣẹ eto aabo l'agbara ni yoo jẹ afojusun wa, pẹlu erongba lati tu awọn agbesunmọmi ati janduku to n gbogun ti awọn eniyan wa ni awọn apa ibi kan ni orilẹede yii
- Mo tun n tun sọ pe gbogbo ọọdunrun akẹkọọkunrin wa ti wọn jigbe nile ẹkọ Government Science Secondary School ni Kankara la ri gba pada
- Bi awọn ọmọ ogun wa, pẹlu ifọwọsowọpọ awọn eeyan mii, ṣe ri awọn ọmọ naa gba pada lai si wahala jẹ ẹri pe Naijiria ni agbara lati koju awọn agbesunmọmi to n koju awọn eniyan rẹ.
Ọrọ Aje
- Afojusun wa ni lati tun ọrọ aje ṣe, nipa oriṣiriṣi ọna ti owo yoo ma a gba wọle, paapaa ipese ounjẹ lọpọ yanturu. O si ti so eso rere, apẹẹrẹ eyi to farahan lasiko isede coronavirsu
- Lọwọlọwọ, a n tun awọn nkan amayedẹrun wa sẹ, lara eyi ti irinna ọkọ oju'rin wa, awọn ojupopo, wa, awọn afara laarin ilu ati igberiko, to fi mọ papakọ ọkọ ofurufu ati ibudokọ oju omi
- Gẹgẹ bi iṣakoso, a n ṣiṣẹ lọwọlọwọ lori oriṣiriṣi eto iranwọ lati pese iṣẹ ati atilẹyin fun awọn ọdọ wa to fẹ ẹ da iṣẹ silẹ
- Bi a ṣe ṣi awọn ibode wa pada, a ni ireti pe okoowo pẹlu awọn orilẹ-ede miran yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje awọn olokoowo keekeeke, ati ẹka iṣẹ agbẹ
- Ki awọn orilẹ-ede to mule ti wa ni Ila Oorun Africa mọ pe awọn to fẹ ẹ ba wa dowo pọ lọna to ba ofin mu nikan la ṣi ibode fun.
Gbigbogun ti iwa ibajẹ
- Se n ṣiṣẹ pẹlu awọn aṣofin, naa ni ao ṣe agbeyẹwo lati tun awọn ofin wa kan sẹ, eyi ti yoo mu ki gbigbokun ti iwa ibajẹ fẹsẹ mulẹ daadaa
- Awa ti a jẹ alaṣẹ yoo ri daju pe awọn to ba jẹbi ẹsun iwa ibajẹ tete foju wina ofin
- A o si tun bẹ awọn to wa ni ẹka idajọ pe ki wọn o fi ọwọ to le mu ẹjọ iwa ibajẹ.
Gẹgẹ bi aarẹ yin ti ẹ dibo yan, ẹjẹ ti ma a jẹ fun yin, gẹgẹ bi iṣe mi ni pe, ma a ṣa ipa mi lai ṣe ojuṣaaju.















