WhatsApp: Ìgbésẹ̀ tó gbé rèé láti mọ̀ bóyá fóònù rẹ̀ kò ní lo áàpù yìí mọ́

WhatsApp: Wo àwọn fóònù ápùù ìfọ̀rọ̀ ránṣẹ́ yìí kò ni bá ṣiṣk mọ́ láti ọjọkini oṣù kíní ọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀pọ̀ ìròyìn lo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ápùù ìfọ̀rọ̀ ránsẹ́ síra ẹni ti a mọ̀ sí WhatsApp, ko ni ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọnù fóònù ìgbàlódé, láti ọjọ́ kini oṣù kíní, ọdún 2021

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020, WhatsApp ko síṣẹ́ mọ lórí àwọn fóònù kan ọdún yìí WhatsApp ko síṣẹ́ mọ lórí àwọn fóònù kan ti wọn n fi Andriod 2.3.7 àti Iphone iOS 8, àwọn tó ti pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣiṣẹ́.

Àwọn fóònù ti WhatsApp kò bá ṣiṣẹ́ mọ́ yìí ni wọ́n pè ní "legacy operating systems'', ti wọ́n ni àwọn kò lé ṣe wàhálà láti mú ko bá ìgbà mu mọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n ni fóònù Android àti Iphone ti o jẹ́ pé àwọn èròjà àtijọ́ nìkàn ló ń lò, kò ni le ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ápùù ti Facebook bá ṣe.

Àwọn tó bá n lo iphone 4 àti àwọn Android tó ti pẹ́, náà ko ni le lo WhatsApp dáada mọ́, tó bá ti di ọdún 2021.

Bákan náà ni WhatsApp kò ni le bá iOS 9 ti ilé iṣẹ́ Apple ṣe lọ́dún 2015.

Àwọn ti kò wá lo fóònù ti Apple ṣe sùgbọ́n ti àwọn fóònù wọ́n ti gòkè àgbà tàbi tó jẹ́ pé Android 4.0.3 sí ló fi n ṣiṣẹ́.

WhatsApp sàlàyé pé ìgbésẹ̀ yìí pọn dandan láti le jẹ́ ki ààbò wà fún àwọn tó kù tó nlo ápùù náà.

Eeyan meji to n tẹ foonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹni ti kò bá wá fẹ́ pàdánù lílo tirẹ̀ yóò ni láti lọ wá èròjà ti yóò fi gbé fóònù tirẹ̀ lárugẹ síi, láti le tẹ̀síwájú ninu lílò rẹ̀.

Àwọn módẹ̀lì bi 4S, 5, 5S. 5C, 6 àti 6S náà yóò nílò ìgbélárugẹ láti le jẹ́ ki WhatsApp máa ṣiṣẹ́ lórí iphone.

Ọdún 2011 ní Android 4.0.3 ti wọn sì tún ṣe àfíkún rẹ̀ lọ́dún tó tẹ̀le.

Facebook

Oríṣun àwòrán, others

Ìgbẹ́sẹ̀ láti máse gba àwọn fóònù tó ti pẹ́ láàyè láti lo WhatsApp mọ́ kìí ṣe ǹkan túntun, nítorí èyí máa n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lé jẹ́ kí àwọn ǹkan èlò wọ́n ni àlò pẹ́ ni.

Bákan náà ni yoo má n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tun le mú ápùù wọ́n wà ní àtúnṣe, ti yóò túbọ̀ wúlò fún àwọn tó n lò ó, pàápàá jùlọ, àwọn tó n lo fóònù tuntun.

Ẹ̀wẹ̀, WhatsApp jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àpùù tó wọ́pọ̀ jùlọ tí àwọn ènìyàn máa ń lò, ti ó sì tó ènìyàn bílíọ̀nù méjì lagbaye tó n lòó.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo WhatsApp lo ti n káyà sókè pé, ṣe awọn kò ni pàdánù lílo WhatsApp báyìí?

Nitori naa, imọran wa fun ẹ ni pe, lọ yẹ fóònù rẹ̀ wò ni "Settings" láti mọ̀ bóyá iOS 9 tàbi Android 4.0.3 lo n lò.