Kidnapping in Nigeria: Arìnrìnàjò kan ṣàlàyé bí orí ṣe ko yọ lọ́wọ́ ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Remi Oladoye
Ọkunrin kan ti ori ko yọ ti salaye ohun toju rẹ ri nidi isẹlẹ ijinigbe to n waye lemọlemọ, paapaa loju ọna Ilesa si Ekiti.
Remi Oladoye, ẹni to salaye bii isẹlẹ naa se waye fun BBC Yoruba ni, ti kii ba se ọpẹ Ọlọrun ati ti awakọ to wa ọkọ ti oun wa, boya isẹlẹ buruku ko ba waye tabi ki oun se ọdun tuntun ni akata awọn ajinigbe.
O fikun pe, agbegbe ilu Erinmo Ijesa si Iwaraja ni ọkọ awọn de lọjọ Aje ana, ni deede aago meje si meje aabọ, to fi se alabapade isẹlẹ ijinigbe to n waye lọwọ lagbegbe naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tó jẹ́ sọ́ọ̀sì nìkàn ni ìjọba ń tìlẹ̀kùn mọ́ torí Covid-19? - CAN
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàíjíríà tó jáde láyé lọ́dún 2020
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola, akọni mánigbàgbé òṣèré tíátà, olórin àti onílù
- Aráàlú dá iná sun èèyàn méjì n‘Ibadan, orí kó ẹni kan yọ
- "Ma a pa ara mi si Cute Abiola lọrun bo ṣe já mi silẹ tori afẹsọna miran"
- "Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà fipá bá ọmọkùnrin mi lòpọ̀ níléèwé Deeper Life, mò ń fẹ́ ìdájọ́"
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín Davido àti Burna boy lórílẹ̀èdè Ghana?
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
"A ri pe ọkan lara awọn mọto to wa niwaju wa duro lojiji, tawọn gende agbebọn to jade lati inu igbo tiiki to wa laarin ilu mejeeji yii si yọ ibọn sawọn ero to wa ninu mọto naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Remi Oladoye
Bi wọn se n ja wọn lole lọwọ, kia ni awakọ tiwa, to ti mọ nipa isẹlẹ to n waye lọwọ naa, nitori ọmọ Efon Alaaye ni, ti fa ọkọ jade lati sẹri pada.
Amọ ibi to yiwọ ọkọ si, agbegbọn miran naa wa nibẹ, to na ibọn si wa amọ awakọ tiwa jafafa pupọ nidi ọkọ wiwa, to si salọ."
Bakan naa lo ni ọkọ meji mii naa fi awakọ toun se awokọse, tawọn naa si fi ere sẹri pada wa si aarin ilu loju ibọn, lẹyin isẹju mẹwa ti ọkọ tiwa ti moribọ.
Akọroyin naa tẹsiwaju pe ọkọ awọn sẹri pada sinu ilu Erinmọ lati duro diẹ ki isẹlẹ naa fi rekọja lọ, ki awọn to tun mu ọna ajo awọn pọn.
O ni nibi ti awọn duro si yii naa lawọn ti n sọ fawọn ọkọ miran to n bọ pe ki wọn mase lọ siwaju nitori ewu to wa lọna.
Awọn arinrinajo miran to tun jajabọ lọwọ ajinigbe:
"Nibẹ ni ọkan lara awọn awakọ naa ti n yi nilẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlarun pe o da ẹmi oun si, ti ko si tun bọ si igbekun awọn ajinigbe.
Awakọ mii ni koda, awọn ajinigbe naa yinbọn mọ ọkọ oun, bẹẹ lo ni oun ko awọn ọmọ oun si ẹyin ọkọ, ta si ri oju ibọn lara mọto rẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Remi Oladoye
Awakọ keji naa si ni oun fi oju oun ri korokoro bayii, tawọn ajinigbe ọhun n ko awọn ero inu ọkọ ti wọn da duro wọnu igbo lọ, ki oun to bọ mọ wọn lọwọ."
Oladoye salaye siwaju si pe awọn araalu ti oun ba sọrọ gan fidi isẹlẹ naa mulẹ pe lemọ-lemọ ni isẹlẹ ijinigbe maa n waye lagbegbe naa.
O ni awọn ọlọdẹ atawọn oloko maa n ri awọn ero to bọ sọwọ ajinigbe ninu igbo, ti wọn yoo ti fẹẹ na ẹlomiran ninu wọn pa.
Iru awọn eeyan wo lo n sisẹ ijinigbe yii?
Nigba ti BBC Yoruba beere pe se o ri irisi awọn eeyan to n sisẹ ibi naa, akọroyin naa ni " A ko ri wọn lọ titi, amọ iwadii mi mi lọdọ awsn to ri wọn fihan pe awọn Fulani ni wọn, ti isẹlẹ naa si tun lọwọ awọn araalu ninu."
Oladoye ni ibi ti isẹlẹ naa ti waye ko to kilomita meji si ibi tawọn sọja duro si, ti wọn ko si yọju rara sibi isẹlẹ naa.
O wa pari ọrọ rẹ pe bi kii ba se pe ọkọ ọhun duro fun isẹju marun lati gbe eeyan kan nilu Efon Alaaye ni, ọwọ awọn ajinigbe naa ni oun ko ba ko si.
O ni boya awọn ẹbi oun ko ba wa ninu pe wọn n wa owo kiri bayii lati ba idande oun lọwọ awọn ajinigbe naa ni.
A n fẹ agbofinro ati Amotekun lagbegbe wa ni gbogbo igba - Elerinmo
BBC Yoruba tun ba ọba alaye lagbegbe naa, Ẹlẹrinmọ tilu Ẹrinmọ, Oba Dokita Michael Adebowale Odunayo Ajayi, Arowotawaya Keji sọrọ nipa isẹlẹ ijinigbe to n waye lemọ-lemọ ni agbegbe naa.
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Ajayi ni lootọ ni isẹlẹ naa waye pẹlu afikun pe asiko ọdun la wa yii, iru isẹlẹ bayii si maa n wọpọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oba Michael Odunayo Ajayi
"Awọn eeyan to n sisẹ ibi yii kii se ara ibi, gbogbo awọn isẹlẹ naa si la ti gbe wa si iwaju ijọba, asofin atawọn agbofinro pe ki wọn dojukọ agbegbe yii daada.
Ibi kii se agbegbe ti wọn yoo maa wa lẹẹkọọkan nitori o yẹ kawọn Amotekun ati Civil Defence wa nibi ni gbogbo igba amọ ko si nkankan nibẹ."

















