Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà
Awọn Fulani yii ti pa ọpọlọpọ eniyan sinu igbo - Omowe Hamzat
Ẹranko làwọn Fulani tó jí mi gbé lọ́nà Ijẹbujẹṣa ṣùgbọ́n ó ní ọwọ́ kan Yorùbá nínú
Ọrọ àwọn Fulani ajinigbe amunipa ni ilẹ̀ Yoruba yii ti n gba ẹbọ lọwọ tonile talejo ni eyi ti apa kan ijọba ko ṣi tii gbagbọ pe o kọja bẹẹ.
Orọ ọhun ti wa di ti ẹni to kan lo mọ lasiko yii.
Omowe Tunde Hamzat ti ori ko yọ ni akata awọn Fulani ajinigbe ni Naijiria ti ṣalaye ohun gbogbo ti oju rẹ ri fun BBC Yoruba.
Omowe Tunde Hamzat ni oun ri aridaju pe àwọn Fulani yii ko ṣiṣẹ wọn lasan.
Wọn ni atilẹyin awọn Yoruba kan to n ba wọn ra ẹya ara eniyan ti ẹbi rẹ ko ba tete san owo itanran.
O ni òde inawo kan ni oun lọ ni Ekiti ki oun to ko sọwọ awọn agbebọn Fulani Darandaran ti wọn n fẹmi ọpọ ṣofo.
Omowe yii ṣalaye ni kikun bi awọn Fulani naa ṣe dira ogun pẹlu ihamọra loriṣiiriṣii.
O ni koko ti oun gba mu ni pe awọn eniyan iran Yoruba kan ti gbabọde ti wọn si n ṣiṣẹ papọ pẹlu àwọn Fulani agbebọn yii.
Omowe Hamzat ni gbogbo iran Yoruba lo wa ninu igbekun yii laimọ nitori ko si ẹni ti ko le ṣẹlẹ si.
Omowe Tunde ti ori pada ko yọ lọwọ awọn Fulani ajinigbe yii sọ fun BBC pé o yẹ ki gbogbo wa jọ gbogun ti awọn Fulani to n ṣiṣẹ ibi yii atawọn Yoruba to n kín wọn lẹyin.
- Àǹfàní n bẹ́ fun Naijiria nínú àdéhùn okòwò ní Afrika, AfCFTA ṣugbọ́n...
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Egypt dá akọ́nimọ̀ọ́gbá Aguirre dúró lẹ̀yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
- Òsìsẹ́ Custom tó dédé sọ ara rẹ̀ di Ọ̀gá Àgbà CG ní àrùn ọpọlọ - Attah
- Amuneke fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Tanzania
O ni asiko ti to ki gbogbo ori ade ati eekan ninu iran Yoruba dide si iwa ipa yii.