AfCFTA: Adùn wo gan ló wà nínú adehun okoòwò kan l'Áfíríkà?

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN PORTS AUTHORITY
Àdéhùn okòwò kan nàà ní Afrika tí orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ tọwọ́ bọ̀ ti ń mú ìbéèrè jáde lórí bó ṣe kan ọmọ Nàìjíríà kọ̀ọ̀kan.
Minisita tẹlẹ ri fun ọrọ katakara ati idokoowo, Okechukwu Enelamah ṣi oju BBC Yoruba si bi Naijiria ṣe pa a ti wọn kun un ti wọn fi ṣe daadaa loju tirẹ pe wọn kọkọ wale wa ronu si i ki wọn to tọwọ bọ ọ.
Aarẹ Naijiria Muhamadu Buhari ṣẹṣẹ fọwọ si adehun okoowo kan naa yii ni nibi ipade apero ajọ iṣọkan ilẹ Afrika to waye ni orilẹede Niger lọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi Enelamah ṣe sọ ọ, o jẹ igbesẹ ti yoo ko ipa pataki ti yoo si ṣe atunto nilẹ Afirika fun odidi ọgọrun ọdun si isisiyii tabi ko tilẹ ju bẹẹ lọ.
O ni ipa ribiribi si ni Naijiria ko ninu iduna dura adehun ọhun.
Naijiria to wa ṣe eyi gan lo wa ni awọn fẹ rii daju pe awọn pe ipade awọn tọrọ kan na labẹle ki wọn to le tọwọ bọ iwe adehun naa.
Ọpọ awọn onwoye lo n beere pe ṣe erongba ibudo okoowo ilẹ Afrika ọhun ko ni foriṣanpọn bayii, nigba ti orilẹede Naijiria to ni eto ọrọ aje to tobi ju lọ ni Afrika, to tun jẹ olori ẹkun Afrika yọwọ kuro ninu rẹ nigba ti awọn to ku n dara pọ mọ ọ.
Awọn tọrọ kan ti aarẹ Buhari pe si ọrọ yii ni bii ẹgbẹ awọn to n pese ọja lorilẹede Naijiria, ẹgbẹ awọn oniṣowo, to fi mọ awọn ijọba ipinlẹ gan lati rii pe wọn ṣe iṣẹ to yẹ ki wọn ṣe na lori igbesẹ pataki yii ki wn to gbe e.
Naijiria kọ lati ṣe bi awọn orilẹede Afirika to ku ṣe ṣe nipa pe awọn kọkọ tọwọ bọwe adehun ki wọn to lọ sile lọ ro o.
Naijiria kọkọ ṣalaye iwulo rẹ, anfani rẹ wọn si gbọ latẹnu awọn tọrọ ọhun kan.
Enelamah ni pẹlu igbesẹ ti Naijiria gbe yii ti wọn jẹ ki araalu mọ ohun ti wọn fẹ ṣe, o fi han pe ijọba awa ara wa fẹsẹ mulẹ daadaa ni Naijiria.
Odidi ọdun kan ni Naijiria fi ṣe eyi ki wọn to wa pinu lati dara pọ.
Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si
Bawo lo ṣe kan araalu lasan ni Naijiria?
Okechukwu Enelamah ṣalaye fun akọroyin BBC pe kii kan kii ṣe fun awọn alagbara ilu nikan, oniruuru ọna lo fi le kan ọmọ Naijiria kọọkan.
- Banki agbaye ti ṣe agbekalẹ awọn Okoowo kekeke, bi wọn ṣe le jẹ anfani awọn nkankan latọdọ ijọba.
- Ile iṣẹ ijọba yoo maa fọwọ si iwe aṣẹ fun ọlọdani lati le kopa.
- Wọn ni anfani ati gba ẹyawo eyi ti ile igbimọ aṣofin ti fọwọ si ti wọn si ti gbe awọn ti yoo maa moju to o kalẹ.
Lori kiko ọja wọle lọna aitọ, Enelamah ni ko tọ naa ni bi apejuwe rẹ ṣugbọn kii ṣe pe tori rẹ kii ṣe pe ki a dawọ pipese ounjẹ fun apẹrẹ irẹsi duro.
Dipo ki o ko ba ọrọ aje, enelamah ni kiko ọja ilẹ okere wọle lọna aitọ gan la gbudọ mu kuro lọna.













