Bí ọwọ́ ọlọ́pàá Kano ṣe tẹ ọkùnrin tó fẹ́ yọ́ wọ ilé ibùsùn obìnrin

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Haruna
Ọwọ ọlọpaa lorile-ede Naijiria ti tẹ arakunrin ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn kan, Umar Ali to mura bi obinrin lati yọ wọ inu ile ibusun awọn akẹkọọ obinrin ile ẹkọ olukọni ijọba apapọ Kano ni ariwa ila oorun Naijiria.
Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ, wọn ni Umar ti ọwọ tẹ lalẹ ọjọ Abamẹta ti jẹwọ pe oun kan fẹ lọ fọwọ kan awọn obinrin naa ni.
Umar bura pe igba akọkọ ti oun yoo hu iru iwa bẹẹ niyii ati pe iya baba oun lo ni hijab ati niqob ti oun wọ lọ ṣe iṣẹ ibi naa.
"Mo bura pe igba akọkọ ree ti maa hu iru iwa yii. Erongba mi si ni ki n wọ aṣọ obinrin wọ inu ibusun wọn ki n si fọwọ kan awọn obinrin. Mo ṣeleri pe mi o ni ṣe iru rẹ mọ''
Umar ti ile rẹ ko jina si ile ẹkọ naa ni ''aṣọ iya baba oun ni aṣọ ti oun ji ati pe bi oun ti ṣe n wọ aṣọ naa ni ọwọ tẹ oun. Ẹ fori ji mi''
DSP Abdullahi Haruna to jẹ alukoro ọlọpaa ni Kano sọ fun BBC pe ni nnkan bi ago mẹwa alẹ ni awọn mu Ali lẹyin ti ọwọ awọn ẹṣọ ile ẹkọ naa tẹ ẹ.
O tẹsiwaju pe awọn yoo gbe e lọ si ile ẹjọ lori ẹsun irina are nitori wọn ko gba awọn ọkunrin laye lati wọ aaye ibusun awọn obinrin akẹkọọ.
O ni kete ti awọn ba ti pari iwadi lawọn yoo wọ ọ lọ si iwaju ile ẹjọ lori ẹsun yii.













