Amuneke fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Tanzania

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Tanzania, TFF fi aridaju han lọjọ aje pe Emmanuel Amuneke ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede naa ni tubi nnubi.
Eyi waye lẹyin ti Taifa Stars ti wọn ṣẹṣẹ kopa ninu idije ife ẹyẹ Nations Cup lati ọdun 1980 ko lee tẹsiwaju mọ ninu idije to n waye ni Egypt tori wọn ja kulẹ lẹẹmẹta.
Ọdun 2018 ni wọn yan ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹri, Amuneke gẹgẹ bii akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Tanzania.
Ati ẹgbẹ agbabọọlu ati akọnimọọgba wọn, Amuneke jọ tọwọ bọwe adehun lati fopin si iṣẹ rẹ gẹgẹ bi TFF ṣe fi si oju opo ayelujara wọn.
Ọgbẹ naa ni awọn yoo yan akọnimọọgba kan na fun 'gba diẹ lẹyin ti awọn ba ṣe ipade pajawiri lọjọbọ ọsẹ oun si ni yoo dari awọn fun idije ife ẹyẹ African Nations Championship (CHAN) eyi ti wọn yoo bẹrẹ loṣu yii.
Amuneke to tun ti jẹ agbabọọlu fun Barcelona ni igbakeji akọnimọọgba Naijiria nigba ti Naijiria jawe olubori ni ife ẹyẹ agbaye FIFA U- 17 fun igba kẹẹrin i UAE lọdun 2013.
Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si
Lẹyin ọdun meji lo dari Naijiria lọ si idije FIFA U- 17 ẹlẹẹkarun un ni chile eyi to mu ki o gba igbega di akọnimọọgba fun ikọ Flying Eagles U- 20.
Gẹgẹ bii agbabọọlu, Amuneke ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu ikọ Super Eagles, oun lo jẹ goolu mejeji ni AFCON 1994 lorilẹede Tunisia nibi ti Naijiria ti fi ami ayo meji si ẹyọkan pẹlu Zambia gba ipo keji nilẹ Afirika.














