AFCON 2019: Egypt dá akọ́nimọ̀ọ́gbá Aguirre dúró lẹ̀yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi nkan ko ṣe ṣẹnu re fawọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Egypt ninu idije AFCON to n lọ lọwọ naa ni wọn ti da akọnimọọgba wọn duro.
Javier Aguirre ni wọn ti ni ko maa lọ ni kete ti Bafanabafana ṣe ti gbo ewuro soju Egypt.
Lalẹ ọjọ Abamẹta ni ẹgbẹ agbabọọlu South Africa fi ami ayo kan sodo le Egypt kuro ninu idije to n lọ lọwọ ti orilẹ-ede Egypt n gbalejo ẹ.
- Kí ló mú kí àwọn èèyàn máa jẹ ọ̀rọ̀ Adeboye lẹ́nu lórí Twitter
- Èyí ni ọ̀nà tí àwọn obìnrin n gbà kó ara wọn sí wàhálà nítorí ara bíbó
- Óya gbé bọ́dì ẹ! Naijiria fi ìgbájú mẹ́ta lé Cameroon kúrò ní AFCON
- Ìdí tí mo fi fẹ́ di Gómìnà Kogi - Dino Melaye
- Kí ló mú ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn án forí la ikú nínú ìkọlù Libya?
Bi wọn ṣe pari ifẹsẹwonsẹ naa ni adari ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni Egypt, Egypt Football Association (EFA) ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Hany Abou-Rida kede ikọwefipo rẹ silẹ pẹlu ileri pe oun ati awọn alaṣẹ EFA gbogbo lawọn jọ n lọ ni.
Bi Egypt ṣe bori lati kopa lẹyin ti idije ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni wọn gba akọnimọọgba ọmọ Mexico naa ko le wa wọn de ebute ogo nipa gbigba ife ẹyẹ AFCON.
Akonimọọgba Aguirre ti kọ wọn ni Japan ati Mexico sẹyin ko to di pe o wa gba ipo Hector Cuper.
Aarẹ ajọ EFA ni oun kọwe fipo silẹ nitori iwa akin to yẹ ni lasiko yii ni Egypt.
O ni oun ti rọ awọn ọmọ igbimọ pata lati kọwe fipo won silẹ bakan naa.
Rida jẹ agbabọọlu nigba kan ri ko to wa gba ipo adari ajọ naa lọdun 2016.
Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu awọn agbabọọlu Egypt lẹyin ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu South Africa.
Akonimọọgba Aguirre ni oun faramọ gbogbo eebu ti awọn eeyan ba n bu oun lori ifidirẹmi naa.
Iṣẹju marun din ni aadọrun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ni Thembinkosi Lorch, agbabọọlu South Africa gba bọọlu sawọn Egypt.

















