Àwọn gómínà ilẹ̀ Yoruba ní àwọn yòò dojú ijà kọ jàndùku Fulani

Awọn gomina apa ila oorun Naijiria, Sanwo-Olu, Akeredolu, Fayemi, Makinde, Oyetola

Oríṣun àwòrán, Osun State Government

Àkọlé àwòrán, A kò lè gba àwọn jandùkú Fulani láàyé nílẹ̀ Yoruba -Awọn gómínà

Ailaṣọ-lọrun pakàá, ti n gba apero ọmọ eríwo bayii ni ipinlẹ Yoruba.

Àwọn gomina ipinlẹ Eko, Osun, Oyo, Ondo ati Ekiti ti n fori kori lati wa ọna abayọ si iṣoro yii.

Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Oyetola, Kayode Fayemi, Seyi Makinde ati Rotimi Akeredolu ti leri wi pe awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati doju ija kọ awọn janduku darandaran to n ṣoṣẹ ni agbegbe naa.

Awọn gomina naa ṣe ipade ni ẹka ile ijọba Ipinlẹ Ondo to wa ni Abuja ni ọjọ Ẹti nibi ti wọn ti fẹnu ko lori ọrọ aabo ni apa ila oorun Naijiria.

Atẹjade kan lati ọwọ adari awọn gomina apa ila oorun Naijiria naa, Rotimi Akeredolu sọ pe o ti di oun to pan dandan bayii lati dẹkun iwa janduku to n gbilẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Khadijat Oluboyo jẹ́rìí ọmọ rẹ̀

Ijinigbe ni awọn opopona bi Ileṣa si Akurẹ, Ileṣa si Iwaraja, Orẹ si Ondo ti di ẹru bi awọn arinrinajo ṣe n mu iroyin ikọlu awọn darandaran wa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Gbogbo àwọn gomina yii lo gba pé ti awọn ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ lasiko, o ṣeeṣe ki ọrọ yii maa gba ẹbọ lọwọ awọn laipẹ.