Akure Anglican Bursar: Àwọn agbébọn gbé owó sálọ lẹ́yìn tí wọ́n pa akápò ìjọ Anglican

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbebọn kan ti yinbọn pa akapo ijọ Anglican lẹkun Akure, Gabriel Abiodun ti wọn si gbe owo ti o lọ gba ni ile ifowopamọ salọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo,Femi Joseph lo fidi ọrọ na mulẹ fun BBC Yoruba.
O ni isẹlẹ naa to waye ladugbo Alagbaka jẹ ajoji si ipinlẹ Ondo.
''O dabi ẹni pe ajoji ni awọn agbebọn to hu iwa yi. Amọ ṣa a ti bẹrẹ iwadi ti ko si ni pẹ ti ọwọ wa yoo fi tẹwọn.''
Ko daju iye owo ti oloogbe naa lọ gba nile ifowopamọ .

Oríṣun àwòrán, Femi Joseph@official
Alukoro ọlọpaa ni nnkan bi ago mọkanla owurọ ọjọbọ ni awọn gburo iṣẹlẹ naa ti o si ni ki awọn to gbe ọgbẹni Gabriel de ile iwosan, o ti dakẹ.
''Wọn tọ lati ile ifowopamọ lọ si ọfisi rẹ ni.Nibẹ ni wọn ka mọ ti wọn ti yinbọn pa ki wọn to gbe owo salọ''









