L'Ondo, àwọn agbébọn jí alága káńsù tẹ́lẹ̀ gbé

Awọn agbebọn to fi iboju bo oju wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iṣẹlẹ ijinigbe ti n di gbọnmọgbọnmọ bayi nipinlẹ Ondo

Awọn agbebọn ti ji alaga tẹlẹ fun ijọba ibilẹ ariwa Akurẹ nipinlẹ Ondo, ọgbẹni Dele Fagoriọla gbe.

Ni ọsan ọjọ abamẹta ni wọn ji i gbe lasiko to wa ninu oko rẹ lopopona akurẹ si Ikẹrẹ Ekiti lati mojuto awọn alagbaro ti wọn n baa ṣiṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Busuyi Fagoriọla to jẹ ẹgbọn rẹ ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun ti wọn to meje niye wọ iboju lasiko ti wọn ji ọgbẹni Dele fagoriọla gbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ni awọn ti bẹrẹ iwaadi lori iṣẹlẹ naa.

Iṣẹlẹ ijinigbe, paapaa jiji awọn oloṣelu ati ọbalaye gbe ti n di gbọnmọgbọnmọ bayi nipinlẹ Ondo.