Ibadan Poly: Àwọn aláṣẹ ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún ìsìnmi nítorí jàgídíjàgan

Ami idanimọ Ibadan Poly

Oríṣun àwòrán, Ibadan Poly

Awọn alasẹ ileewe giga gbogboniṣe Polytechnic Ibadan ti gbe ilẹkun ileewe naa ti pa.

Eyi waye lẹyin ti rogbodiyan waye laarin awọn akẹkọọ kan nileewe naa.

Bakan naa ni wọn ti fi ofin de gbogbo nkan to ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ akẹkọọ nileewe naa.

Igbimọ to n mojuto awọn ileeṣẹ iroyin ninu ọgba ileewe naa, jabọ loju opo ayelujara rẹ pe wọn fi nkan gun akẹkọọ kan to jẹ oludari ere idaraya fun awọn akẹkọọ imọ ẹrọ, Oyeniyi Tobi.

Bakan naa ni akẹkọọ mi i naa tun farapa lẹyin ti wọn lu u ni alubami.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, wahala naa bẹrẹ lẹyin idije bọọlu gbigba to waye laarin awọn akẹkọọ imọ ẹrọ ati awọn akẹgbẹ wọn to n kọ nipa nipa okoowo ati ibaraẹnisọrọ.

Eyi lo fa a ti awọn alaṣẹ ileewe naa fi paṣẹ pe ki gbogbo akẹkọọ fi ọgba ileewe naa silẹ ni kiakia, ki wọn o si lọ fun isinmi idaji saa ni tipa-tipa.

Àkọlé fídíò, BBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe

Alukoro ileewe giga naa, Alhaji Adewọle Ṣọladoye sọ fun BBC Yoruba pe gbogbo awọn akẹkọọ to farapa nibi iṣẹlẹ naa lo ti n gba itọju nileewosan to jẹ ti ileewe.

Bakan naa lo sọ pe ọjọ kẹwa, oṣu Kẹrin ni awọn akẹkọọ naa yoo to pada si ọgba ileewe.

'A ko ti i le sọ igba ti ẹgbẹ akẹkọọ (SUG) yoo pada bẹrẹ, nitori pe nkan to kọkọ jẹ wa logun ni eto ẹkọ wọn, kiiṣe ọrọ ẹgbẹ.''

Nibayii, awọn ọlọpaa ti wa ninu ọgba ileewe naa lati ṣewadii lori iṣẹlẹ shun ati lati dena wahala to ba tun le fẹ ẹ bẹrẹ.