Ìjọba Ọ̀sun: N1.8bn ni OAU jẹ lówó orí òsìsẹ́ rẹ̀

Ẹnu iloro fasiti OAU

Oríṣun àwòrán, Bose

Àkọlé àwòrán, Bílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù náírà, (1.8 bílíọ̀nù) ni fásitì OAU jẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Àjọ tó ń pawó wọlé lábẹ́lé, tó tún ń se kòkárí ówó orí nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, OIRS, ti gbé ìloro ọgbà fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ tó wa nílùú Ilé ifẹ̀ tì pa lórí ẹ̀sùn pé, ó jẹ owó orí to dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù méjì náírà.

Owó orí tí fásitì OAU jẹ la gbọ́ wí pé, ó jẹ́ owó orí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ, èyí tí kò san sínú aṣuwọ̀n ìjọba ìpínlẹ̀ náà lọ́dún 2015 si 2016.

iloro fasiti OAU ti wọn ti pa

Oríṣun àwòrán, Bose

Àkọlé àwòrán, Fásitì OAU ṣàlàyé pé àìgbọ́raẹniyé láàárín fásitì àti ìjọba ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Àjọ náà gbé ìloro ọgbà fásitì náà tì pa lẹ́yìn tí gbèdéke ọjọ́ méje tí wọn fún OAU làti san owó orí ọ̀hun forí sánpọ́n.

Kùtùkùtù òwúrò ọjọ́rú làwọn òṣìṣẹ́ ikọ̀ amúṣẹ́yá láti àjọ olówó-orí ípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, OIRS, gúnlẹ̀ sí ọgbà fásitì náà, tí wọ́n sì ti gbàgede ìgbìmò alákòóso tó ga jùlọ níléèwé náà ati ọ́fíísì ìṣàkóso níbẹ̀.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n mórí lé ìloro ọgbà fásitì náà tí wọ́n sì fi ẹ̀wọn tìí, ṣùgbọ́n wọ́n fi ààyè ìrìnnà ẹsẹ̀ sílẹ̀.

Osisẹ ajọ OIRS n lẹ iwe mákàn mọ ileewe naa

Oríṣun àwòrán, Bose

Àkọlé àwòrán, Gbèdéke ọjọ́ méje ni wọ́n fún fásitì náà làti san owó orí ọ̀hun.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé náà, ollórí ikọ̀ amúsẹ́yá fọ́rọ̀ owó orí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, ọ̀gbẹ́ni Ọládípọ̀ Babátúndé ní, bílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù náírà, (1.8 bílíọ̀nù) ni fásitì náà jẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí wọn kò sì san-án nígbà tí gbèdéke tí wọ́n fún wọn pé.

Awọn ọkọ to lati wọle si ọgba fasiti OAU

Oríṣun àwòrán, Bose

Àkọlé àwòrán, Kùtùkùtù òwúrò ọjọ́ ọ̀rú làwọn òṣìṣẹ́ ikọ̀ amúṣẹ́yá láti àjọ olówó-orí nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, OIRS gúnlẹ̀ sí ọgbà fásitì náà

Àmọ́ ṣá, àwọn aláṣẹ fásitì náà ti ṣàlàyé pé, àìgbọ́raẹniyé láàárín fásitì náà àti ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

"Fásitì yìí ti bẹ̀rẹ̀ sísan àjẹẹ́lẹ̀ gbèsè owó orí náà láti ọdún 2017 ṣùgbọ́n òbítíbitì gbèsè owó orí tàwọn ìṣàkóso tó ti lo ìgbà kọjá jẹ sílẹ, ló ń fa wàhálà yii."