Awakọ kan d'oloogbe ninu ikọlu afurasi darandaran nipinlẹ Ondo

Fulani darandaran kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iroyin sọ pe awakọ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn k'agbako nipinlẹ Ondo

Iroyin sọ wipe afurasi Fulani darandaran kan ti pa ọkunrin awakọ kan ti orukọ rẹ njẹ Victor Ajisafe nitori aigbora-ẹniye ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo.

Fulani darandaran naa ti awọn akọroyin ko le e fidi orukọ rẹ mulẹ, fi ẹsẹ fẹẹ lẹyin isẹlẹ naa lagbegbe Road Block, ni Akure.

Iroyin sọ pe awakọ to jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn, jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹgbẹ awakọ, NURTW nipinlẹ naa.

Awọn ti isẹlẹ naa sojurẹ wi pe, lara awọn ọrẹ Fulani darandaran naa, Usman Olaniyi lo sọ fun un wipe, ọkunrin awakọ naa n sọrọ odi si, loba fa ọkọ yọ, ti o si seku pa ọkunrin awakọ naa.

Alukoro ajọ ọlọpa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph to ti fidi isẹlẹ naa mulẹ, sọ pe awọn ọlọpa ti bẹrẹ iwadi lori ọrọ naa.

Joseph wi pe wọn ti fi panpẹ ọlọpa mu Usman ati awọn ọrẹ rẹ, sugbọn ọwọ sikun wọn ko tii mu fulani darandaran naa.

Alukoro ajọ ọlọpa ipinlẹ Ondo naa sọ siwaju wi pe, awọn yoo gbe Usman rele ẹjọ, nitori pe ohun ni o sokunfa ija naa, ti wọn ko ba ri Fulani darandaran ti o na papa bora.