Wo àwọn ìlérí tàwọn Gómìnà tuntun ṣe nínú ìbúra wọn

Oríṣun àwòrán, NIG/PRESIDENCY
Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019 ni wọn ṣe ibura fun aarẹ Buhari lẹekeji pẹlu awọn gomina tuntun.
Ni Gbagede Eagle Square ni wọn ti bura fun aarẹ Buhari ati Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo to jẹ igbakeji rẹ nibi ti arẹ Buhari ko ti ka ọrọ akọsọ rẹ fun igba akọkọ ninu itan Naijiria.
Buhari búra láti bọwọ fún ofin Naijiria ni saa keji rẹ.
Awọn gomina ti wọn bura fun ni awọn ipinlẹ wọn naa ṣe awọn ileri kan fawọn ara ilu ni eyi to maa mu ki ọsan so didun ti wọn ba muu ṣẹ.
BBC Yoruba ṣagbeyẹwo diẹ lara awọn ileri ti wọn ti n fọn rere ẹ koda ṣaaju eto ibura wọn
Gomina Abdulrazaq Abdulrahman ti ẹgbẹ́ oṣelu APC ti wọn bura fun lati tukọ ipinlẹ Kwara titi di 2023 ṣeleri lati ṣatunṣe si eto ọgbin atawọn ohun amayedẹrun.

Oun lo le igba oṣelu PDP wọle ni Kwara pẹlu 'O tó gẹ'.
Bakan na lo tun ṣeleri lati tun awọn opopona ṣe ati mimojuto gbigbẹ odo Niger ki opin de ba omiyale ni Kwara paapaa lati ẹkun Patigi.
Mo kéde ìlú-kò-fararọ lori eto ẹkọ ipinlẹ Yobe! - Mala
Gomina Mala Buni to maa tukọ ipinlẹ Yobe di 2023 ni oun ti ṣetan lati kọ opọlọpọ ile iwe alakọbẹrẹ ati ti girama pupọ sii.
O ni oun mọ ọṣẹ́ buruku tawọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram ti ṣe ni ẹkun yii to ti sọ eto ẹkọ wọn di nkan miran.

Oríṣun àwòrán, @Bego
Maa tún àwọn Kọmiṣọnna tó ba ṣiṣẹ daadaa lò lẹẹkansii- Gomina Ebonyi
Gomina Dave Umahi ti ipinlẹ Ebonyi ṣeleri láti ṣe itọju awọn arugbo ni saa iṣejọba rẹ ikeji yii

Gomina Dave lo gboriyin fawọn to baa ṣiṣẹ sẹyin pe wọn gbiyanju.
O ṣeleri lati ri si itọju awọn obinrin, ati lati mojuto eto ilera awọn ewe sii.
Ganduje: mo ṣetań lati pèsè ẹkọ ọ̀fẹ́ fawọn Akanda ẹ̀dá
Gomina ipinlẹ Kano to ṣe ibura lẹẹkeji, Abdullahi Umar Ganduje ni saa keji oun yii, awọn akanda ẹda a gbadun ẹkọ ọfe lati ile iwe alakọbẹrẹ titi de ti girama ni.

Oríṣun àwòrán, @Yakasai
Sanwo Olu- Ijọba mi ko ni yọ ẹnikẹni silẹ nipinlẹ Eko
Babajide Sanwo Olu to jawe olubori gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣe ọpọlọpọ ileri fawọn olugbe ipinlẹ Eko.

Sanwo Olu ki àwọn eniyan ipinlẹ Eko fun ifarada si bi igba ti ri lasiko yii.
O ni ki wọn fọkan balẹ nitori didun ni ọsan ipinlẹ Eko yoo so nitori itẹsiwaju Eko lo jẹ oun logun.
Sanwo Olu ni ijọba oun yoo jẹ eyi to n gbọ ọrọ awọn ara ilu to dibo yan oun.
Mo wọgile gbogbo iṣẹ́ akanṣe tijọba to kọja lọ ti gbe sita tẹlẹ- Yahaya ipinlẹ Gombe
Gomina Inuwa Yahaya ti ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle bayii ni ipinlẹ Gombe.

Oríṣun àwòrán, @yahaya
Gomina tuntun fun ipinlẹ Gombe ni oun ko ni tẹlẹ awọn awuyewuye to ti n waye lati oṣu kẹta ni Gombe rara.
O ni ipade apero tẹẹkoto ti gomina PDP tẹlẹ n ṣe ni Gombe ti dopin bayii nitori pe omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ inu iṣejọba ipinlẹ Gombe bayii.
Ẹ darijin mi, Maa gbe igbesẹ to yẹ bayii- El Rufai
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El Rufai to ṣe ibura lẹẹkeji lati tun tukọ ipinlẹ Kaduna ti tọrọ aforijin lọwọ awọn eniyan Kaduna.

Oríṣun àwòrán, @Elrufai
Nasir El Rufai ni oun n bẹbẹ silẹ nitori pe ijọba oun ti ṣetan lati gbe awọn igbesẹ akin to yẹ ni saa yii.
O ni oun n riran ọjọ iwaju rere to kun fun owó ati iṣẹ lọpọ yanturu fawọn eniyan ipinlẹ Kaduna ni saa iṣejọba keji oun yii.
Dapọ Abiọdun: Mo kọ̀ láti ko ẹ̀bi mi nikan si ijọba mi
Gomina tuntun ti wọn bura fun lati tukọ ipinlẹ Ogun di 2023 ni ko nii si adanikan jẹ ninu iṣejọba oun nipinlẹ Ogun rara.

Dapo Abiọdun ni oun bura lati fi ootọ inu ṣiṣẹ si alaafia ati idagbasoke awọn eniyan ipinlẹ Ogun lapapọ ni.
O ni oun ko ni da ẹnikẹni ninu adehun ati awọn ileri ti oun ti ṣe ṣaaju idibo.
Ni papa iṣere MKO Abiola to wa ni Kutọ, nilu Abẹokuta ni Dapo ti ṣeleri lati ṣe atunṣe si igbe aye awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun.
Alaafia eniyan Enugu lo jẹ mi logun -Ugwuanyi

Oríṣun àwòrán, @ugwuanyi
Gomina Ifeanyi Ugwuanyi lo jawe olubori labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Enugu ninu idibo ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta, ọdun yii.
O ni oun yoo gbajumọ eto aabo awọn eniyan oun ni saa keji ti o ṣẹṣẹ ṣe ibura rẹ yii.
Mo wọgile #3,000 tawọn akẹkọọ ipinlẹ Oyo n san - Makinde
Seyi Makinde to jawe olubori labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni yoo tukọ ipinlẹ Oyo titi di ọdun 2023.

Ìjọba Naijiria ti ṣe ìlérí lóríṣíiríṣi látẹnu àwọn Gomina tuntun ti wọ́n ṣe ìbúra ni àná ni èyí tó lè mú ọsàn so dídùn fáwọn ara ilu.



















