Europa League Final: Chelsea lu Arsenal ní àlùdákú ní Baku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alubami ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea na Arsenal pẹlu ami ayo mẹrin si ẹyọ kan ni ifẹsẹwọnsẹ asekagba ti Europa League fun ọdun 2019.
Agbabọọlu Chelsea, Giroud lo kọkọ si san bantẹ iya fun Arsenal to jẹ ikọ rẹ tẹlẹri, ki Pedro ati Hazard to pari iya naa fun Arsenal.
Amo, Alex Iwobi ti Arsenal naa ko jẹ ki iya naa ko jẹ awọn gbe, bẹẹ lo da ẹyọkan pada fun Chelsea, ti ayo naa si pari si 4-1.
Igba kẹfa niyi ti ikọ agbabọọlu Chelsea yoo ma koju Arsenal ni ifẹsẹwọnsẹ to jẹ asekagba Europa League.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Chelsea vs Arsenal, gbẹgẹdẹ yóò gbiná ní Europa League Final!
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kuna ni igba mẹrin ninu maarun, ti wọn ti de asekagba idije naa, ti wọn si jawe olubori ni 1994 CWC.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti jawe olubori fun igba mẹrin, ti meji jẹ ti CWC, Uefa Cup ati CL.
Kante ati Giroud pẹlu awọn agbabọọlu mọkanla lo kọkọ side ifẹsẹwọnsẹ fun ikọ Chelsea, nigba ti Aubameyang ati Lacazette yoo ma a gba fun Arsenal gẹgẹ bi agbabọọlu mọkanla akọkọ.










