Nigeria Swearing in 2019: Makinde ní omi tuntun rú, ìgbà ọ̀tun dé sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura fun nipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe alaye wi pe, asiko ti to fun imuṣẹ awọn ileri ti oun ṣe lasiko ipolongo idibo.
Makinde fidi ọrọ naa mulẹ ni Ọjọru, lẹhin to bura wọle gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, eyi to waye ni papa Iṣere Ọbafẹmi Awọlọwọ, tokalẹ si opopona Liberty niluu Ibadan.Ohun akọkọ ti gomina wọgile ni igbesẹ sisan ẹgbẹrun mẹta naira, ti awọn ọmọ ilẹ ẹkọ girama n san nipinlẹ Ọyọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ṣe alaye wi pe, ko bojumu ki awọn obi maa lakaka ki wọn to ri owo san fun awọn ọmọ wọn to n bẹ nile ẹkọ girama to jẹ ti ijọba.Ṣeyi Makinde tun mẹnuba pataki eto ẹkọ ati igbiyanju rẹ lati mu ko di irọrun f'awọn akẹkọọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe, bii ẹgbẹrun lọna irinwo akẹkọọ ni ko lanfani lati tẹsiwaju lẹnu ẹkọ wọn nipinlẹ Ọyọ, nitori ipenija owo.
O ni, "A ba obi awọn ọmọ to n lọ si ile ẹkọ girama to jẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ sọrọ, a si ṣe awari ẹ pe, gbogbo wọn n tiraka lati san ẹgbẹrun mẹta naira ti ijọba ana n gba lọwọ wọn. Lati asiko yii lọ, mo paṣẹ gẹgẹ bii gomina wipe ki wọn wọgile sisan iru owo bẹẹ."

- Gomina Makinde tẹsiwaju wi pe omi tuntun ti ru nipinlẹ Ọyọ, igba ọtun si ti de pẹlu.Ọ̀tá Nàíjíríà ni Saraki àti Dogara - Buhari
- Nigeria swearing-in: Ọjọ́ kò! Ìbúrawọlé Nàìjíríà ṣojú àgbáyé
- Dúkìá mi ò lé kan o, mo ti dá fọ́ọ̀mù padà bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Buhari, Osinbajo
- Ìtàn ayé Seyi Makinde, gómìnà tuntun ní Ọ̀yọ́
O ni, "lasiko ipolongo idibo, bi a ti n lọ lati jọba ibilẹ kan si ikeji, a tẹti gbọ ẹdun ọkan ti awọn eeyan ni.
Mo mọ pe ohun ti awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ n beere fun ko pọ ju.
A ba awọn olokoowo sọrọ lori awọn ipenija to niṣẹ pẹluu owo ori sisan."

- "Bakan naa ni a ba awọn agbẹ sọrọ ni awọn agbegbe bii Ipapo, Ilora, Eruwa, Ogbomosho, Iresaadu, Ijaiye, Akufo ati Lalupon.Gbogbo wọn si ni wọn n mi imi ẹdun nipasẹ aisi eto ẹyawo lati le ṣe iṣẹ wọn botiyẹ.Èèyàn 5 farapa, ọ̀pọ̀ ọkọ̀ jóná nínú ìjàmbá iná márosẹ̀ Ibadan sí Eko
- Ta ni Babajide Sanwo Olu, gomina tuntun l‘Eko?
- Ìtàn ìgbé ayé Abdulrahman Abdulrazak, gómìnà Kwara
- Aṣọ ń pe aṣọ ránṣẹ́ ni lásìkò ìbúra gómìnà àti ààrẹ
Awọn agbẹ naa sọrọ lori awọn ipenija ti wọn n dojuko nitori aisi awọn ohun elo amayedẹrun, paapa ọna to ja gara lasiko ti wọn ba fẹ ko ere oko.

- Iṣakoso ti wa yoo mu ipese ohun elo amayedẹrun lọkunkundun".Lori owo awọn olukọ to jẹ oṣiṣẹ fẹhinti, Ṣeyi Makinde ṣe ileri lati fi owo oṣu rẹ gẹgẹ bii gomina gbọ bukata wọn.Ò ṣe f'ọ́mọ tí ń jeérú! Chelsea wọ Arsenal lẹ́wù ìyà ní Europa pẹ̀lú 4-1!
- Ọlọ́pàá Adamawa ni #30,000 ni wọ́n fi bọ́ igún látìmọ́lé
- Wo àwọn míniístà mẹ́fà tí ẹnu ń kùn jùlọ
Lasiko to n sọrọ lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju, Makinde ni lọwọlọwọ bayii, ipinlẹ Ọyọ ko lee san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira fawọn osisẹ.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Sugbọn o salaye pe bi ohun gbogbo ba lọ botiyẹ, o ṣeeṣe ki owo osu oṣiṣẹ nipinlẹ Ọyọ jẹ eyi ti yoo pọ julọ loriẹede Naijiria.
Gomina tuntun naa wa dupẹ lọwọ awọn lẹgbẹlẹgbẹ, loyeloye to fimọ awọn adari ẹgbẹ oṣẹlu to ṣe atilẹhin fun un lasiko ipolongo idibo.
O ṣe ileri wipe, oun yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bii gomina to ni eero awọn ara ilu lọkan.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Lara awọn eeyan pataki to peju-pesẹ sibi ayẹyẹ iburawọle naa ni adajọ agba nipinlẹ Ọyọ, Muktar Abimbola ati aṣoju alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹkun guusu orilẹede yii.
Awọn yoku ni gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayoṣe, gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ Adebayọ Alao Akala, Olubadan ti ilẹ Ibadan Ọba Saliu Adetunji, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi ati bẹẹbẹẹ lọ.


















