Donald Trump: ṣàbẹ́wò ọlọ́jọ́ mẹ́ta sílẹ̀ gẹ̀ẹ́sì

Wo àwọn àwòrán tó làmì-laaka nínú àbẹ̀wò Donald Trump àti Melania aya rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́sẹ̀ yìí.

trump
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trump to n dari ilẹ Amerika ati iyawo rẹ, Melania Trump ni wọn jọ de si UK lọjọ Aje nínú baalu Air Force One.
trump
Àkọlé àwòrán, Saaju abẹwo yii ni Trump ti fihan pe oun wa lẹyin Boris Johnson pe ko gba ipo Theresa May.
trump

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Aàrẹ Donald Trump àti Melania aya rẹ̀ jẹ oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lù Obabìnrin Elizabeth ni Buckingham Palace lọjọ kinni abẹwo naa.
trump
Àkọlé àwòrán, Trump àti Melania aya rẹ gbé òdòdó ìrántí sójú oórì akọni lójú ìjà
trump
Àkọlé àwòrán, Wọn yan bi ológun ki Aarẹ Donald Trump kaabọ silẹ̀ Gẹẹsi
Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde fọn feere to jọ Aarẹ Trump lọmọ ọwọ́ ni Parliament Square
trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Trump ṣe ipade pẹlu Theresa May ni St James Palace lẹyin to kuro ni Buckingham Palace lọdọ Obabinrin Elizabeth
trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Okọ ayọkẹlẹ Cardillac "Beast' ni o gbe Aarẹ Trump ati aya rẹ lọ si Downing street fún ipade naa.
trump

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Phillip ọkọ Theresa May ati Trump ati aya rẹ jọ ya fọto lẹyin ipade lori ọrọ Hauwei ti China
Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Iwọde waye kaakiri UK bii ti eyi to bẹrẹ ni Trafalgar Square pẹlu ere Trump to n yagbẹ sinu ṣalanga oni goolu
trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Omooba Charles ati aya rẹ pẹlu Trump ati aya rẹ jẹ ounjẹ alẹ nile aṣoju Amerika ni Regents Park
Trump

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Obabinrin Elizabeth, Omooba Charles, Trump, Macron, Theresa May atawọn olori orilẹ-ede mii nibi ayẹyẹ D Day to waye
Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trump ati Melania n dagbere ni Southampton nibi ti wọn ti wọ Air Force One to n gbe wọn lọ si Ireland