Ọlọ́pàá Ìpínlẹ Ondo: Egúngún tó pa ọ̀dọ́kùnrin yóò fojú ba Ilé- Ẹjọ́

Àkọlé fídíò, Femi Joseph: Egungun to pa ọdọkunrin yoo foju ba Ile- Ẹjọ

Ile-Isẹ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ Ondo ti fi panpẹ ọba mu eleegun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Olu Olowokere lori ẹsun pe o gun arakunrin kan to sẹsẹ ri isẹ pa.

Agbẹnusọ ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph to sọ pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, ni iwadii nlọ lọwọ lori isẹlẹ naa.

Alukoro Ọlọpaa naa fikun wi pe awọn ti fi panpẹ ọlọpaa mu olori awọn eleegun naa ni ipinlẹ Ondo.

Egungun

Oríṣun àwòrán, NAiraland

Àkọlé àwòrán, Ilé-Isẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ Ondo ti fi pańpẹ́ ọlọ́pàá mú arákùnrin eléégún tó sekúpa ọmọkùnrin kan ní ìlú Akure.
Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

Awọn ti ọrọ naa se oju rẹ ni Ọkunrin ti wọn sekupaa naa, Femi Makanjuọla lọ ra ounjẹ lasiko ti awọn eleegun naa bere owo lọwọ rẹ, ti o si kọ lati fun wọn.

Wọn ni Makanjuọla sẹsẹ ri isẹ pẹlu Ile-Isẹ Dangote Cement Company , ti o si yẹ ko lọ bẹrẹ isẹ ni Ọjọ Aje, ọsẹ yii.

Amọ eleegun ti wọn fẹsun kan naa wi pe o pa ọmọkunrin naa, Olu Olowokere sọ wi pe oun ko lo pa arakunrin naa.

Wọ́n fipá bá ọmọbìnrin ogún ọdún lò pọ̀, wọ́n sì pa á

SEUN

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Àkọlé àwòrán, Gomina Ìpínlẹ̀ Ondo tí kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí arábìnrin tí àwọn agbẹ́nipa fibá ba lopọ̀ tí wọ́n sí pa á ní ìlú Akure.

Gomina Ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti pasẹ fun ile-isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo latiri wi pe wọn wa awọn ẹni to pa ọmbinrin ogun ọdun ni ipinlẹ Ondo.

Ọmọbinrin ti orukọ rẹ n jẹ Motunrayọ Seun Ajila ni o ṣetan lati Ile-Iwe Giga, Adeyemi College of Education, Ondo ti awọn kan si fi ipa baa lopọ ni adugbo Sunday Bus Stop, Akure.

Ninu atẹjade ti Gomina Akeredolu fi lede lati ọwọ akowe eto iroyin rẹ, Arakunrin Segun Ajiboye to sọ pe gbogbo agbegbe to wa ni ipinlẹ Ondo ni awọn yoo ri daju pe awọn ṣe idaabobo to peye fun.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo àrà tí ẹ le fi gèlè dá láàrín ìṣẹ́jú mẹ́ta

Akeredolu to kẹdun pẹlu ẹbi ati ara ọmọbinrin to doloogbe naa ni oun yoo ri daju wi pe awọn to sekupa ọmọbinrin naa ko lọ lai fi oju wina ofin.

Gomina Ipinlẹ Ondo naa wa parọwa si awọn ọdọ lati ri wi pe wọn se isẹ takuntakun lati jẹ eniyan nla lai gba ọna ẹburu, ki ọjọ iwaju wọn le dara.

Àkọlé fídíò, È gbọ àlàyé lẹnu àwọn ti ójúẹlẹgba leko irú iṣẹ ti oògùn olóró má n ṣé lara.
Àkọlé fídíò, Àwa obìnrin tó ń lépa afòjúsùn máa n ba ọkùnrin lẹ́rù ni -Toyin Lawani