Osun Election 2018: Àwọn ọlọ́pàá fi tajútajú tú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP tó fẹ̀hónú hàn nítorí ìbò Ọṣun

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu
Wahala nla bẹ silẹ l'ọjọ Ẹti lasiko ti ẹgbẹ́ alatako googi ni Naijiria, PDP, ṣe iwọde niluu Abuja.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fi ẹhonu han niluu Abuja, ti wọn si fi ẹsun kan iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari pe o fẹ ẹ ba eto oṣelu awaarawa jẹ ni Naijiria nitori eto idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Ọṣun, nibiti ẹgbẹ oṣelu APC ti jawe olubori.
Ṣugbọn ko pẹ ti iwọde naa bẹrẹ ni awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni wọ iya ija pẹlu àwọn to n ṣe iwọde ọhun, ti wọn si da afẹfẹ tajutaju si agbegbe ti iwọde naa ti n waye.
Olori ile igbimọ asofin agba ati asoju-sofin l'Abuja Bukola Saraki ati Yakubu Dogara wa lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP to wa nibi ifẹhonu han naa.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP f'ẹ̀sùn kan Ààrẹ Muhammadu Buhari pé wọ́n fẹ́ ba ètò ìṣèjọba àwaarawa jẹ́ ní Nàìjíríà.
Alukoro ẹgbẹ́ nàá, Kọla Ologbondiyan, sọ pé àwọn yóò gbé ìwé ẹ̀sùn nàá lọ sí ọ̀dọ̀ àjọ INEC àti iléèṣẹ́ ọlọ́pàá.
Ologbondiyan sọ fún BBC pé àwọn n fi ẹ̀hónú hàn nítorí ìhùwàsí àjọ INEC lórí ọ̀nà tó gbà ṣètò ìdìbò gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọṣun.

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Facebook
Asọjú ẹgbẹ́ APC, Gboyega Oyetọla ni wọ́n kéde lẹ́yìn tí àtúndì ìbò wáyé. Olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ PDP, Ademọla Adeleke ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tó kọ́kọ́ wáyé.
Ologbondiyan ní ìjọba apápọ̀ àti ẹgbẹ́ APC fẹ́ ẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ da ètò ìṣèjọba àwaarawa Nàìjíríà jẹ́ ni. Àti pé ó yẹ kí àjọ INEC dá dúró láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
Ó ní ṣùgbọ́n àjọ INEC n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀ka kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tó wà ní ìṣàkóso.
Ṣugbọn, ajọ INEC sọ fun BBC l'ọjọ Ẹti pe awọn ko jẹbi ẹsun ṣiṣe mago-mago lasiko eto idibo gomina to waye ni ipinlẹ Ọṣun ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi kan awọn.
Akọwe ikede fun alaga ajọ INEC, Rotimi Oyekanmi sọ pe ajọ naa ko fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ osṣelu kankan lati jale ibo ni Ọṣun.
Ọgbẹni Oyekanmi sọ pe awọn seto idibo gomina l'Ọṣun ni ibamu pẹlu bi awọn ṣe maa n ṣe eto idibo lọdọọdun, paapa ọdun 2015.
Kọla Ologbondiyan sọ pé èsì ìbò tí INEC kéde ní ìpínlẹ̀ Ọṣun kò bá òfin mu, tó sì yẹ kí ọ̀gá àgbà fún INEC, Mahmood Yakubu kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, PDP
Oyekanmi sọ pe 'eto idibo to waye l'Ọṣun gan an lo ti i daraju ninu gbogbo idibo gomina ti ajọ naa ti ṣe, nitori bi awọn eroja idibo ṣe tete de si awọn ibudo idibo, ati pe ni nkan bi i aago mẹjọ aarọ ni ida mejidinlọgọrun awọn ibudo naa ti wa ni ṣiṣi.
Àwọn kọmisana ajọ INEC meji to ba àwọn to sẹ iwọde ọhun sọrọ, May Agbamuche-Mbu ati Mohammed Haruna, sọ pe ajọ INEC ti pinnu lati ṣe eto idibo ti ko ni i ni ikunsinu ninu l'ọdun 2019.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Oyekanmi sọ pe "irọ ni PDP pa pe ajọ INEC n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC.
"Nigba ti ẹgbẹ PDP wa ni iṣakoso, ẹsun kan naa ni ẹgbẹ oṣelu APC fi kan INEC pé a n ṣe atilẹyin fun wọn, ṣugbọn ni bayii ti APC naa ti wa nipo, PDP naa tun n sọ ẹsun kan naa.
INEC sọ pé ki ẹgbẹ́ PDP fi ọkan balẹ, pe wọ́rọ́wọ́ ni eto idibo 2019 yoo lọ, ti ko si ni i si mago-mago kankan.












