Osun Supreme Court: PDP ní iléẹjọ́ ti sọ tirẹ̀, kò sí ohun tí ẹnikẹ́ni leè ṣe si

Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubaka, ti fesi si idajọ ile ẹjọ ga julọ nilẹ wa, eyi to ni Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ APC ni ojulowo gomina Ipinlẹ Osun,
Atiku loju opo Twitter rẹ ni, ipa Adeleke ninu oṣelu ko ti i dopin bo tilẹ jẹ pe o ja kulẹ niwaju ile ẹjọ.
O ni oun ki Adeleke ati awọn ara Osun fun aduroti wọn, bẹẹ si ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Osun naa ni awọn gba idajọ naa wọle
Alaga PDP ni Osun, Soji Adagunodo sọ fun awọn akọroyin wipe, ile ẹjọ ti sọ tirẹ, ko si si ohun ti awọn le ṣe si.
Gẹgẹ bii ọmọ Naijiria to n pa ofin mọ, mo gba idajọ ile ẹjọ to ga ju lọ lai fi ohunkohun ṣe - Ademola Adeleke.
Ninu idahun tirẹ, Ademola Adeleke to jẹ oludije ninu idibo naa to waye nin 2019 ni yatọ fun gbogbo ikunsinu ti oun ni ati gbogbo ohun ti inu oun ko dun si, ohunkohun ti ile ẹjọ giga ju l ba sọ ni abẹ ge.
Ninu atẹjade ka ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi sita, Adeleke ni gẹgẹ olufẹ ijọba awa ara wa to n pa ofin mọ, oun gba idajọ ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, "Gboyegaoyetola, @IsiakaAdeleke1
Latari eyi, Adeleke ki gomina Gboyega Oyetola ku oriire o si ni oun fẹ rere fun un.
Ṣaaju, Aarẹ orilẹede Naijiria atawọn eekan mii ti n fi ọrọ ikini ranṣẹ si gomina ti ile ẹj to ga ju lọ fontẹ lu gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola.
Aarẹ Buhari fi si oju opo Twitter rẹ pe oun gboriyin fun awọn ara ipinlẹ Osun ti wọn fi aaye gba idọgba labẹ ofin o si jẹjẹ atilẹyin iṣejọba rẹ fun un.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni ti Gomina Gboyega Oyetola oni nkan gan funra rẹ, ohun to sọ ko ju bayii lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bakan naa, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to wa nilẹ Amẹrika fi ọrọ ikini wọn ránṣẹ si gomina Oyetola.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Femi Gbajabiamila to jẹ adari ile igbimọ aṣoju ṣofin gan ko gbẹyin plu ọrọ ikini rẹ si gomina Oyetola.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4