CAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria
Eeyan fẹrẹ le maa maa jade laini ọlọpaa lẹ́gbẹ̀ mọ ni Naijiria -Samson Ayorinde
Alufaa Samson Ayokunle to n dari ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ba BBC Yoruba sọrọ lori eto aabo Naijiria paapaa ti ẹkun iwọ oorun to mẹhẹ lasiko yii.
O ni ọrọ ti ijọba n sọ pe irọ ni pe wọn n ji awọn eniyan gbe tabi pe ko to odiwọn ti awọn eniyan n pariwo n kọ oun lominu pupọ.
Alaga ẹgbẹ Christian Association of Nigeria sọrọ lori iriri rẹ nipa awọn to ti kagbako agbebọn fulani darandaran ni eyi to jẹ ki oun le fi gbogbo énu sọ pe oniṣẹ ibi wa ninu wọn.
Alufaa samson Ayokunle ni Ìkọlù àwọn Fulani darandaran àti ajínigbé ti ń gba ẹbọ lọwọ tẹru tọmo bayii ni Naijiria.
O ni ẹni to kan lo mọ ni ọrọ ọhun lo fi dabi pe ko ka ijọba lara tó.
Alufaa yi ke gbajare si gbogob agbaye lati dide wa ran Naijiria lọwọ lati koju eto aabo wa.