A nilo agọ ọlọpaa ni Orin Ekiti fún aabo wa -Falua

Àkọlé fídíò, A nilo agọ ọlọpa ni Orin Ekiti fún aabo wa -Falua

A nilo agọ ọlọpaa ni Orin Ekiti -Joseph Falua

Opolopo igba ni ikọlu ti maa n wa ni Orin Ekiti ti awọn ole maa n fẹ wa ji nkan ninu igbo ọba to wa nibẹ.

Eyi lo mu ki awọn agba ilu ṣa ara wọn jọ gẹgẹ bii ọdẹ ti wọn si n ṣo ara wọn ati ilu.

Alagba Joseph Falua to jẹ olori ilu yii ni aìsi agọ ọlọpaa ni ẹkun Ekiti yii lo n jẹ ki wọn maa ṣagbako awọn oniṣẹ ibi yii

Ni kete ti wọn gba ipe pe ole n ja ni igbo ọba ni Alagba Emmanuel Ilori ti pe awọn ọdẹ ẹgbẹ rẹ to ku ti wọn si jọ lọ gbiyanju lati daabo bo ọrọ ijọba ni agbegbe wọn.

Iku lo gbẹyin iṣẹ akin ti Ogbeni Ilori lọ ṣe yii nitori wọn ni awon afurasi Fulani kan ya bo wọn ti wọn si yinbon fun wọn.

Ogbeni Peter Dada, ọkan lara awọn ọdẹ ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ni pe nigba ti ibọn ko ran wọn ni awọn afurasi yii ba gun wọn ni eyi to jasi iku fun oloogbe.

Oloogbe yii jẹ ọmọ ọdun mejilelọgọta.

Iku akin to n pa akinkanju lo pada mu ẹmi oloogbe Emmanuel Ilori lọ.

Nigba ti BBC kan si awọn ọlọpaa ni ẹkun yii, wọn ni iwadii ṣi n lọ lọwọ.