Cute Abiola: Mo ti n bá agbẹjọ́rò mí sọ̀rọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ òfin lórí ẹ̀ṣùn náà

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Yoruba ni ọrọ ifẹ, bii adanwo ni, oro ọfa ifẹ si mu ju oro abẹ lọ ninu ọkan.
Boya eyi lo mu ki ọmọbinrin kan, Victory Omogiate fi n leri leka pe oun le gba ẹmi ara oun nitori ijakulẹ ifẹ to ba pade lati ọdọ gbajumọ adẹrinposonu kan lori ayelujara, Cute Abiola.
Bẹẹ ba ri iroyin naa ka, ọjọ ọdun Keresimesi ni alawada naa, Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin, ti ọpọ tun mọ si Ankara Gucci, gbe soju opo Instagram rẹ pe oun ti ni iyawo afẹsọna, ti orukọ rẹ n jẹ Adedamola Adewale @Adeherself.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà fipá bá ọmọkùnrin mi lòpọ̀ níléèwé Deeper Life, mò ń fẹ́ ìdájọ́"
- Ẹ̀ lajú yín, ayédèrú ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò COVID-19 gbòde kan l‘Eko - Ìjọba figbe ta
- Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
- ₦9.4bn ní rìbá táwọn agbẹjọ́rò fún adájọ́ láàrín ọdún mẹ́ta - ICPC
- Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo
- Wọ́n gún ọkùnrin kan lọ́bẹ pa torí ó tako yínyin báńgà sínú Mọ́ṣálásí
- Àwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020 pẹ̀lú ìtàn lórí bí wọ́n ṣe jáde
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- N kò tíì pa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tì, bí mo tilẹ̀ ti kúrò nílé ọkọ - Mercy Aigbe
Amọ nigba ti Victory ri ikede yii ka, lo ba kede loju opo Twitter rẹ pe @dysel pe Cute Abiola ti lu oun ni jibiti ara, ti ikede nini afẹsọna naa si fẹ da oun lori ru.

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Bakan naa ni ọmọbinrin ọhun n sepe pe awọn afẹsọna mejeeji naa ko ni ri ayọ ninu igbeyawo wọn tori Cute Abiola lo oun nilokulo ni aimọye igba.
"Kii se pe o fi tipa ba mi lopọ amọ o dibọn bi ẹni pe o nifẹ mi, o si ti pẹ ju fun mi ko to ye mi pe o kan n lo mi ni.
Lootọ n ko ni ẹri to daju lọwọ nitori mo ti pa ọpọ itakurọsọ wa loriayelujara rẹ, ti mo si ro pe sise bẹẹ yoo jẹ ki n tete gbagbe rẹ ati awọn nnkan to sẹlẹ laarin wa."

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Victory ni ki ẹnikẹni mase da oun lẹjọ nitori wọn ko mọ isoro ti oun n la kọja lati bi ọdun kan sẹyin, to si tun fi aworan ti oun ati Cute Abola ya soju opo Twitter rẹ́, lasiko ti ọrọ wọn wọ.
O ni "Nigba ti Abiola fi atẹjisẹ ransẹ si mi, ẹnu ya mi, tori oju opo Instagram mi la ti kọkọ bẹrẹ nibi to ti ni oun fẹ maa ba mi jade.
Bi o tilẹ jẹ pe mo lọ tikọ saaju lati gba fun, amọ nigba to ya mo fun ni nọmba mi, ta si bẹrẹ si ni sọrọ lọsan loru, to si n yọ mi lẹnu pe oun fẹ ba mi dọrẹ pọ."

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Victory fikun pe oun ati adẹrinposonu naa bẹrẹ si ni ajọsepọ, ọjọ kan si wa to dabi ẹni pe oun tabuku ara oun nipa gbigbe nnkan ọkunrin rẹ sẹnu lasiko ti awọn n sere ifẹ, bẹẹ lo tu omi nnkan ọkunrin si oun lẹnu.
"Mo ro pe mo ti ri ọkọ temi ni lai mọ pe o kan n lo mi lati gbadun ara rẹ ni, ti n ko si le gbagbe bo se sọ mi di oniyẹyẹ.
Ọmọbinrin naa ni lẹyin ti Cute Abiola ti seleri aye ati ọrun fun oun, lo wa ja oun ju silẹ, lẹyin to ti lo oun tan.

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
"Ko si to ba mi ni ajọsepọ, ni mo ti sọ fun pe emi kii se oninabi, amọ to seleri fun mi pe oun ko ni ja mi kulẹ laelae."
Victory ni ọrọ bi Cute Abiola yii se ni afẹsọna naa gbọdọ jẹ irọ nla, bẹẹ si ni to ba sẹ pe irọ ni oun n pa, oun setan lati gbe awọn aworan ihoho rẹ to wa lori foonu oun sita.
Bakan naa lo dunkoko pe ti oun ba gbẹmi ara oun, Abdulrazak Abiola lo faa, oun si ni ki wọn mu pe o pa oun nitori bo se kede pe oun ti ni afẹsọna ti ba oun lọkan jẹ lọpọlọpọ.

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Iha wo ni Cute Abiola kọ sawọn ẹsun naa?
Awọn idunkooko ọmọbinrin naa lo mu ki BBC Yoruba kan si Cute Abiola, ti ọpọ eeyan tun mọ si Lawyer Kunle lati gbọ tẹnu rẹ, ka si wadi ododo daju nipa awọn ẹsun ti ọmọge yii fi kan.
Nigba to n ba wa sọrọ lori isẹlẹ naa lorukọ onibara rẹ, agbẹjọro fun Cute Abiola, Amofin Fatai Adebanjo ni ẹsẹ ofin ni awọn yoo fi yanju ọrọ naa.
"Onibara mi sẹsẹ fi ọrọ naa to mi leti ni, a si ti n fẹ gbe igbesẹ to tọ sofin lori rẹ, bi a ba si fẹ gbe igbesẹ ofin, ko yẹ ki onibara sọ ọrọ kankan lori ayelujara lori rẹ."

Oríṣun àwòrán, @victoryomogiate
Bakan naa lo fikun pe gbajumọ ti aye mọ ni mọ ni onibara oun, nitori naa, eeyan kan ko kan le wa lati fẹ fi onibara oun gun oke nitori iru iwa bayii pọ nilu ta wa yii, obinrin naa si kan fẹ jẹun ni lati bẹyin bẹbọjẹ fun onibara oun.
"Awọn ọrọ ti obinrin yi sọ, tawọn ọjọgbọn ba gbe yẹwo, ejo lọwọ ninu, to si foju han pe ọmọbinrin yẹ sa pamọ sawọn abẹ ika kan, a si ti fala sawọn ọrọ kan ti ọmọbinrin naa sọ, eyi to fihan pe ọrọ rẹ ko rinlẹ to."
















