Omo Ibadan: Ó wù mí láti kàwé di dókítà oníṣègùn òyìnbó tàbí ọ̀mọ̀wé ni Fáṣítì - Lizzy Jay ọmọ Ibadan

Lizzy Jay

Oríṣun àwòrán, Lizzy Jay

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja adẹrinposonu nì, Adebola Adeyela, ti gbogbo eeyan mọ si Lizzy Jay ọmọ Ibadan tí salaye nipa ọpọ ohun ti oju rẹ n ri ni agbo iṣẹ amuludun.

Lizzy Jay ọmọ Ibadan, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, oun kii ṣe ọmọ Ibadan rara, oun kan n ya ede Ibadan lo ni, lati ṣe awada.

Adebola, tii ṣe ọmọ bibi ilu Ile-Ife ni oun n ṣe awada naa, nigba ti ọwọ oun dilẹ ni, lai mọ pe o lee di nkan nla, ti awọn eeyan kii si jẹ ki oun gbadun, ti oun ko ba ṣe.

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe ile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo gba oun wọle sile ẹkọ fasiti naa, ti oun si ni lẹta igbaniwọle si fasiti naa lọwọ amọ fun iyalẹnu oun, asiko ti oun fẹ ṣe iforukọsilẹ nile ẹkọ naa ni oun ri pe, wọn ti yọ orukọ oun kuro ninu awọn to fẹ wọle sile ẹkọ naa.

Ọmọ Ibadan, to ni oun ti ni iwe ẹri diploma kekere taa mọ si OND lọwọ tun salaye pe, ni kete ti oun padanu eto igbaniwọle si fasiti Obafemi Awolowo naa, ni oun ba kuku pada lọ sile ẹkọ Poly, lati gba iwe ẹri diploma agba, tii ṣe HND.

Lizzy Jay ọmọ Ibadan ni, iṣẹ orin kikọ gan ni oun fi bẹrẹ iṣẹ amuludun, ti oun ko si fi awada ti oun jọ ti ẹnikẹni, tabi fi ẹnikẹni ṣe awokọse.Nigba to n sọrọ lori ibasepọ rẹ pẹlu alawada miran lori ayelujara ti wọn n pe ni Cute Abiola, lizzy ni ọrẹ timọ-timọ oun ni ọmọkunrin naa, ti awọn si dijọ ma a n ṣe awada papọ lori ayelujara.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Instagram

O fikun pe "awọn obi mi ko tako awada ti mo n ṣe lori ayelujara, koda wọn n gbaruku ti mi ni, gbogbo ohun ti mo ba fẹ, si ni wọn maa n ba mi fẹ.

" Ọmọ Ibadan ni awada ori ayelujara naa ti gbe oun de awọn orilẹ ede lorisirisi loke okun, to si gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn tẹra mọ ohunkohun tí wọn ba da wọle daadaa lai rẹwẹsi.

Lizzy, ẹni to sọrọ nipa ipenija to n koju ninu iṣẹ to yan laayo naa ni, "oju obinrin tó wa lagbo amuludun n ri to, nitori ọpọ ilọkulọ ti wọn n fi lọ obinrin, to si jẹ pe obinrin ko le wọ awujọ kan, lai jẹ pe ọkunrin ni yoo mu lọ sibẹ."

"Dokita oníṣègùn oyinbo gan lo wu mi ki n ṣe lati kekere, nigba to ya ni ẹbun orin kíkọ jẹ jade lara mi, mo dara pọ mọ ẹgbẹ akọrin, lẹyin naa ni mo wa bẹrẹ ere apanilẹrin.

" Lizzy Jay ni ohun to kan fun oun bayii ni lati dara pọ mọ awọn elere tiata, ti oun si fẹ maa kopa ninu sinima ṣiṣe."Sibẹ sibẹ, o si wu mi lati kawe si, amọ yoo jẹ loke okun.

O si wu mi ki n kawe di dokita onisegun oyinbo, amọ bi eyi ko ba ṣee se, mo fẹ kawe gba oye ọmọwe PhD, ki n si di ọmọwe dokita.

"Ọmọ Ibadan wa gba awọn ololufe rẹ nimọran lati maa bọwọ fun ofin to rọ mọ idena itankalẹ arun Coronavirus nitori ewu to wa ninu ajakalẹ arun naa.

Èdè Gẹ̀ẹ́sì tí pọju nínú tíátà Yorùbá tá n gbé jáde lóde òní - Afeez Ọwọ

Oṣere tiata Yoruba ti awọn eeyan mọbi ẹni mowo nni, Afeez Ọwọ ti bẹnu atẹ lu bi awọn oṣere tiata Yoruba ṣe n faye gba ede oyinbo pupọ ninu ere sinima wọn.

Afeez to sọ ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto BBC Yoruba loju opo Facebook ni, bi iṣesi yii ko ba dẹwọ, o le ṣe akoba fun idagbasoke ede Yoruba.

Aworan Afeez Ọwọ ati Mide Martins

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialafeezowo

Yatọ si arọwa to pa yii, o tun mẹnu ba awọn koko ọrọ miran to ni ṣe pẹlu irinajo rẹ lagbo oṣere tiata ati ibaṣepo laarin oun ati iyawo rẹ, Mide Martins.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Igi to ba dara kii p nigbo lọrọ Funmi Martins

Lara awọn nnkan ti Afeez mẹnuba ni iya iyawo rẹ Funmi Martins, ati ipa to ko ninu igbesi aye oun ati iyawo rẹ Mide Martins.

O sọ pe Funmi Martins jẹ abiyamọ tootọ ti o si jẹ ẹni to fẹran gbogbo eniyan sugbọn to jẹ pe, iku se emi rẹ legbodo lai pe ọjọ.

Iya to bimi ko fki n sere tiata

Afeez Ọwọ, nigba to n salaye irinajo rẹ laye sọ pe iya to bi oun ko fi taratara gba pe ki oun maa ṣe ere tiata.

Aworan Afeez Ọwọ ati awọn ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/mydemartins

O ni nigba ti oun wa ni kekere, gbogbo ọna lati dari ọkan oun kuro nidi ere tiata ni iya oun maa n wa, amọ akọsilẹ ti ko pe ere tiata lọna oun.

''Ni ibẹrẹ igbesi aye mi, iya to bi mi ko ri ere tiata bii nkan gidi, fun idi eyi, ko fẹ ki n yan isẹ naa laayo sugbọn loni, opẹ ni fun Ọlorun''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: