LASEMA: Àwọn ohùn tó lè gbiná tó wà níbi ìtajà Balogun ló dá kún ìjà iná tó ṣàkóbá níbẹ̀
Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko ti ṣalaye pe awọn ohun to le gbina bi bẹntiroo ati ẹrọ amunawa tawọn eeyan gbe sinu ṣọọbu lo dakun ijamba ina ọja Idumota nilu Eko.
Ọgbẹni Oke Osanyititolu lo sọ ọrọ yi fawọn akoroyin nibi iṣẹlẹ ina naa.
O ni lọwọlọwọ bayi ko ti ṣi ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ninu alaye rẹ bakanna o ni awọn n gbiyanju lati dkun ina ohun ṣugbọn airaye de ibi ina naa nitori bi awọn ile itaja ti ṣe fun pọ jẹ ipenija nla.
O wa rọ awọn eeyan to n taja nibẹ lati ri wi pe wọn ko gbe ohun to le gbana si inu sọọbu wọn.


Bi ọrọ naa ti ṣe n lọ
Lowurọ ọjọ Iṣegun ni iroyin gbode pe ibudo itaja nla kan ni ina ọhun ti bẹrẹ, ti gbogbo oju ọna to wọ inu ọja naa si ti di patapata.
A gbọ pe ibudo itaja naa lo wa ni ojule kẹtalelogoji, opopona Martins lagbegbe Lagos Island nilu Eko.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ọhun ti wa fikun pe awọn osisẹ panapana ti de sinu ọja naa lati bomi pa ina naa ko to pẹju.
Bẹẹ si ni awọn ontaja to wa ninu ile itaja naa ti n ko ẹru wọn to ku ti ina ko tii ba, ki wọn le doola rẹ lọwọ ina to n jo naa.

Bẹẹ si ni awọn ontaja to wa ninu ile itaja naa ti n ko ẹru wọn to ku ti ina ko tii ba, ki wọn le doola rẹ lọwọ ina to n jo naa.

Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti wa n kigbe loju opo Twitter wọn pe ki ijba tete jara mọ igbesẹ pipa ina ọhun.
@SubDeliveryZone tiẹ fi aworan bi ina ọhun se n jo soju opo Twitter rẹ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post













