Border Closure: Wíwó laá wó àwọn ilé ìkẹ́rùpamọ̀sí tó wà láwọn ibodè wa

Mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @GeoffreyOnyeama

Ijọba apapọ ti kede erongba rẹ lori ibode orilẹede Naijiria to ti di titi pa. Ijọba ti kede ohun marun un to gbọdọ di mimu ṣẹ ki ibode to le di ṣiṣi pada.

Minisita ọrọ ilẹ okere, Geoffrey Onyeama jiroro pẹlu awọn ọmọ igbimọ ti ijọba yan lati sọ asọyepọ lori ọrọ ibode to wa ni titi pa.

Ijọba ti ti ibode Naijiria pa fun bi ọsẹ melo bayii lati jẹki ọrọ aje le gberu sii ati lati dena kiko ẹru wole lọna aitọ.

Ọpọ lo ti n ṣorọ lori igbesẹ ijọba yii, bawọn kan ṣe tako igbesẹ ọhun, lawọn mii n gboṣuba fun ijọba pe ohun to tọ ni ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ṣe lori ibode titi pa.

Kọda ijọba to sọ pe o di oṣu kinni ọdun 2019 ki ohun to gbero lati ṣi ibode naa pada nitori igbesẹ naa ti ilọsiwaju ba ọrọ-aje Naijiria.

Wọnyi lawọn ohun ti ijọba sọ pe pe o gbọdọ ṣẹlẹ ki ibode to le di ṣiṣi pada:

Ko gbọdọ si atundi ẹru to n wọle mọ

Idi akọkọ nipe ko gbọdọ si atundi ẹru to ba n wọle lati orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ ECOWAS si orilẹede mii to jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS bakan naa.

Ijọba ni iru ẹru bẹẹ gbọdọ lọ sọdọ awọn oṣiṣẹ aṣọbode, bẹẹ ni ẹnikan ko si gbọdọ fọwọ kan an.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Awọn ọja ECOWAS ko gbọdọ tapa sofin

Idi miiran ti ijọba tun sọ nipe gbogbo ọja ti wọn ba n ko wọ Naijiria lati awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ ECOWAS gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ofin ati ilana ajọ naa.

Àwọn ilé ìkẹ́rùpamọ́sí lẹ́bàa ibode gbúdọ̀ di títì pa

Idi eleyii sọ pe wọn gbudọ̀ bọwọ fun ofin ibilẹ eyi to nii ṣe pẹlu kiko ọja wọle ati pe ki wọn ti awọn ile ti wọn ma n kẹru pamọ si to wa lagbegbe ibode.

Onyeama sọ pe awọn ti pinu lati wo gbogbo ile ikẹrupamọsi to ba wa lọna gbogbo awọn ibode wa kaakiri.

O ni pataki ju lọ ni pe kiko ẹru wọle gbudọ wa pẹlu ibọwọ fun ofin abẹle "tori naa a gbudọ lodi si ki wọn maa pa ọja ti ni Naijiria".

Àkọlé fídíò, Mo ti sọ ìran nípa ọkọ aképo tó gbiná ní Onitsha kó tó ṣẹlẹ̀ - Prinmate Ayodele