Border Closure: Ibodè títì lè fa rògbòdìyàn láàárín orílẹ̀èdè méjì

Border Closure

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Àwọn ènìyàn ń jẹ̀yà lórí ibodè tí wọ́n tìpa - Olókòwò

Onimọ nipa Idokowo,Tope Fasua ti ni ibode titi pa le fa rogbodiyan laarin orilẹede Naijiria ati awọn orilẹede ti wọn yi i ka.

Fasua fesi si ọrọ yii lasiko ti wọn fi lede wi pe o seese ki wọn tilẹ ṣi ibode naa ninu Oṣu Kini, ọdun to n bọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni titi ti wọn ti ibode naa ti mu ifasẹyin ba ọrọ aje awọn eniyan ti wọn n ṣe karakata laaarin orilẹede Naijiria ati omiiran.

‘Awọn ara Ghana tilẹ ni awọn ko ni pẹ ti ibode naa ti ijọba Naijiria ko ba gbọ ẹbẹ wọn pe ki wọn ṣi ibode.

Onimọ nipa idokowo ọhun ni ati mẹkunu ati olowo ni ibode ti wọn ti naa ṣe akoba fun.

Tope Fasua wa rawọ ẹbẹ si ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣada, ki wọn si ṣi ibode ki awọn ti wọn ko lowo lee ri owo fi ṣe ọdun.

A lè má ṣí ibodè ní Ósù Kíní, ọdún 2020 - Ọ̀gá Àgbà Custom

Ile iṣẹ Asọbode Naijiria ti ni ko pọn dandan fun awọn lati ṣi ibode Naijiria ni Oṣu Kini, ọdun 2020.

Alukoro Ajọ naa, Joseph Attah lo fi lede pe Osu Kini, ọdun to n bọ ni awọn yoo kọkọ pari igbesẹ wọn lati ri abayọrii titi ibode Naijiria.

Aworan ọgba ileeṣẹ asọbode Naijiria Hameed Alli

Oríṣun àwòrán, Facebook/customsng

Attah ni ibode Naijiria yoo wa ni titi pa titi di igba ti orilẹede Naijiria ba kẹsẹjari ninu ilakaka wọn lati jẹ ki ọrọ aje gbe pẹẹli soke.

Bakan naa ni wọn fi kun un wi pe, ibode naa yoo wa ni titi pa titi awọn orilẹede to yi Naijiria ka yoo fi bọwọ fun ofin to rọmọ karakata ni ilẹ Iwo-Oorun Afirika.

Iléeṣẹ́ asọ́bodè: Kò jọọ́ ,gbọingbọin la ó ti ẹnu ibodè Nàìjíríà pa di Oṣù kíni 2020

Fawọn to ba lero pe ileeṣẹ aṣọbode Naijria yoo jẹ ki awọn ọja kan wọle lasiko Keresimesi ti n bọ yii ,ọrọ ko ri bẹẹ.

Idi ni pe Ileeṣẹ aṣọbode orileede Naijiria ti sun ọjọ ti wọn yoo ti ibode Naijiria pẹlu awọn alabagbe rẹ pa titi di oṣu kini ọdun 2020.

Ikede yii ti wọn fi ista ninu atẹjade kan ni ọga ileeṣẹ naa kan Victor Dimka buwọlu lọjọ kini oṣu Kọkanla ọdun 2019.

Ninu iwe naa, ileeṣẹ naa sọ pe t'oun ti bi awọn ti ṣe ṣe aṣeyọri to lamilaka pẹlu bode tawọn ti pa 'ASarẹ Buhari ṣi ni ki awọn tẹiwaju pẹlu titi ibode naa di oṣu Kini ọdun 2020.''

O tẹsiwaju pe owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣọbode to fi mọ owo epo ọkọ ti wọn yoo lo yoo jẹ ssisan laipẹ.

Aworan iwe ti ajọ aṣọbode fi kede isunsiwaju titi pa bode

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sumner Shagari Sambo

Bi a ko ba gbagbe orileede Naijiria gbe igbesẹ lati ti ibode rẹ pẹlu awọn orileede to jẹ alabagbe rẹ lati le dẹkun fayawọ irẹsi ati awọn nkan tẹnu n jẹ miiran.

Igbesẹ yi tawọn kan sọ pe o tako ofin karakata ajọ ECOWAS ni o ti mu ki awọn alabagbe Naijiria bi Benin ati Ghana ma kerora.

Koda awọn orileede miiran bi Thailand ati Vietnam naa ke gbajare si ijọba Naijiria lati ṣi ibode ki awọn ọja wọn baa le wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: