Ajọ EFCC yóò bẹrẹ ìwádìí lórí ìwà màgòmágó láàárín elétò àbò

Diezani

Oríṣun àwòrán, @diezani

Àkọlé àwòrán, EFCC kò lẹ́tọ lati ta ǹkan iní Dieziani si ilẹ̀ okere

Ajo to n ri si Iṣowo ilu baṣubaṣu, EFCC, ti ni awọn yoo yi oju ina pada bayii si gbogbo ẹka eto abo ilẹ yii.

Ibrahim Magu to jẹ olori ajọ naa, lo fi ọrọ yii lede ni ilu Abuja nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ

Magu wi pe, asiko ti to wayii lati tanna wadii gbogbo magomago to ti waye lawọn ẹka eto abo nilẹ yii bẹrẹ lati ọdọ awọn ọlopaa, ọmọ ogun,ati ti awọn ọtẹlẹmuyẹ.

O ni ajọ naa ni wọn ri bi eyi ti o saba maa n gbogun ti iwa ibajẹ laarin awọn oṣiṣẹ ṣugbọn bayii wọn yoo yẹ gbogbo inawo awọn ẹka naa wo finifini.

Alaga naa wi pe ajọ yii ni wọn yan pelu ojugba rẹ ti ICPC lati gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ to fi mọ awọn eka toku fun ti o boju to iwa ibajẹ lawujọ.

Ko i ṣai mẹnu baa wi pe ṣaju asiko Aarẹ Buhari ni ajọ naa jẹ eyi ti o n tanna wa iwa ibajẹ awọn oṣiṣẹ, oloṣelu ati ti ile ifowopamọ nikan.

O ṣalaye pe ajọ naa kọju si bi wọn ṣe ṣe owo ti wọn fi ra awọn nkan ija ogun ni ọdun 2015, ti ọpọ awọn ọga agba ologun si jẹbi ẹsun naa ti wọn si foju ba ile ẹjọ.

Ni bayii , o ni ajọ naa tun kọju ija si awọn aluni ni jibiti ori afẹfẹ ti a mọ si yahoo- yahoo,pẹlu ajọsepọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ile okeere [FB].

Bakan naa ni ajọ naa ti ni awọn yoo lu gbogbo eru ati ẹṣọ olowo iyebiye ti wọn ri gba pada lọwọ Diezani Madueke ni gbanjo si ilẹ okeere.

Ṣugbọn awọn agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti o n ri si bi ati n lu eru ni gbanjo lorilẹ ede yii ti bẹnu atẹ lu alaga ajọ EFCC lori ọrọ naa wi pe ko tọna lati taa si oke okun.

Wọn ni niwọn igba to jẹ wi pe owo ilẹ yii ni arabinrin naa ji lati ko ọrọ jọ, ilẹ yii naa lo yẹ ki wọn ta si ati pe, ẹgbẹ wọn lo yẹ ki Ijọba lo lati ṣe iru eto bẹẹ.

Ẹni ti o jẹ akọwe ẹgbẹ naa, Isibor Benjamin Abhulimen ni o fesi si ọrọ ti Magu sọ lorukọ gbogbo ẹgbẹ pe ko boju mu rara lati gbe tita awọn eru naa fun ara ilẹ okeere.

Ṣe ṣaaju ni ile ẹjọ kan ni ilu Eko nibi ti adajọ Nicholas Oweibo ti ni ki Ijọba Apapọ gba gbogbo goolu olowo iyebiye ati ile nla ti arabinrin naa fi ọna eburu kojọ.