Muhammadu Buhari: Ààrẹ Nàìjíríà gba Saudi lọ sí ìlú London nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahamad
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti mori le ilẹ Gẹẹsi bayii lati orilẹede Saudi Arabia, lẹyin to kopa ninu eto Umrah ati apero kan to niiṣe pẹlu idokowo lọjọ iwaju.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe, lọsan ọjọ Satide ọjọ keji oṣu kọkanla l'aarẹ filu Makkah silẹ lọ siluu London.
Aarẹ Buhari kopa ninu apero idokowo naa fun ọjọ mẹta to bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn eleyi to pari ni ọjọ kọkanlelọgbọn niluu Riyadh.
- Ẹni kan ti gbẹ́mìí mì; àwọn mẹ́rin ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn-LASEMA
- Mátikú; Oba ìlú Eko tó forí oyè sílẹ̀ lọ́dún 1931 kí àlàáfíà lè jọba
- Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Olùdásílẹ̀ FIN
- Mo ń bá ọ́kùnrin 15 sùn lọ́ọ̀jọ́ láti sàn owó ọ̀gá mi- Ngozi
- Wo orílẹ́èdè tí wọ́n tí ń dáwó ìsìnkú ara wọn pámọ́
- Mo bu ọlọ́pàá jẹ nígbà tó fẹ́ yín mi lọ́rùn ní Mushin- Àáfà
Aarẹ Buhari ṣepade pọ pẹlu Ọba ilẹ Saudi, Mohammed bin Salman lori bi ajọṣepọ to dan mọran yoo ṣe wa laarin Naijiria ati orilẹede Saudi sii lori ọrọ epo rọbi ati ati afẹfẹ gaasi.
Ninu ipade ti wọn jọ ṣe papọ, Ọba Saudi pe fun idasilẹ ajọ kan ti yoo maa ṣe igbelarugẹ idokowo laarin Naijiria ati Saudi.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bahir Ahmad
Ẹwẹ, awọn gomina mẹta ti wọn kọwọọ rin pẹlu aarẹ Buhari lọ si Saudi Arabia ti pada silu Abuja.
Amọ, aarẹ Buhari rinrin ajo lọ si London pẹlu diẹ lara awọn iṣomọgbe rẹ ti wọn jọ lọ Saudi.








