Lagos crime: Àáfà ní òun bu ọlọ́pàá jẹ nígbà tó fẹ́ yí òun lọ́rùn ní Mushin

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Police

Àkọlé àwòrán, Lagos crime: Àáfà ní òun bu ọlọ́pàá jẹ nígbà tó fẹ́ yí òun lọ́rùn ní Mushin

Ki oju ma ri ibi, gbogbo ara loogun rẹ. Eyi lo difa fun aafa kan, Abdulfatai Solahudeen ti wọn sọ pe o bu awọn ọlọpaa jẹ.

Solahudeen ni wọn gbe lọ sile ẹjọ Magisireti lagbegbe Ogba niluu Eko ni Guusu Naijiria.

Awọn ọlọpaa mu ọkunrin yii to tun n fi Ọkada gbero lori ẹsun pe o n ṣiṣẹ ju akoko ti ofin gba a laaye lọ.

Ni bi aago mejila oru ku iṣẹju mẹẹdogun ni ọlọpaa Seyi Akindele ati awọn akẹgbẹ rẹ mu aafa yii ni Mushin nigba ti wọn n ṣe iwọde de agbgbe naa.

Irọyin sọ pe Solahudeen n wọ ya ija pẹlu awọn ọlọpaa nigba ti wọn mu un, lẹyin naa lo bu ọkan lara wọn jẹ lọwọ.

Amọ, ninu ọrọ rẹ, Solahudeen to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji sọ pe oun bu ọlọpaa ọun jẹ nitori o fọwọ fun oun lọrun.

Aafa naa ni oun n fi Ọkada ṣiṣẹ lati pese ounjẹ fun idile oun, bakan naa lo sọ pe oun maa n kun Ọkada nigba tọjọ ba ti lọ lati ri owo gidi nibẹ.

Nigbẹyin gbẹyin, ẹsun onikoko mẹta to da lori idoju ija kọ eeyan ati aigbọran sofin oju popo ni wọn fi kan an.

Àkọlé fídíò, Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil

Amọ, Solahudeen loun ko jẹbi ẹsun ti wọn kan oun, lẹyin naa ni ileẹjọ gba oniduro rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Adajọ, Iyaafin O. Ogundare sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kokanlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019.