Saudi Arabia: Ìtàn kíkùn lórí Mọ́ṣáláṣí Anabi tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 1440 sẹyin.

Oríṣun àwòrán, @Alshaw
Mọṣalaṣi yii lo tobi ṣikeji to tun lamilaaka ninu eyi ti Anabi Muhammed (SAW) ti kirun.
Lọdun 1909 ni wọn kọkọ tan ina kaakiri rẹ ni ilẹ Larubawa gẹgẹ bi Sultan Ghalib Al Quaiti ṣe sọ ninu iwe rẹ : The Holy Cities, the pilgrimage and the world of Islam.

Oríṣun àwòrán, @Aquabi
Iatkun agbaye mọṣalaṣi nla yii ni ori ilẹ 143, 000 saare ilẹ ni mita ni wọn fi kọ mọṣalaṣi naa.
Itan fihan pe lẹyin mọṣalaṣi ni Mecca, ko si mọṣalaṣi miran ni gbogbo agbaye ti awọn eniyan ka si mimọ ju ti Medina yii lọ.
Mọṣalaṣi Mecca ati ti Medina yii ni wọn ka si eyi to mọ julọ ni eyi ti wọn fi n pe wọn ni Al-Haramainush Sharifain ninu ede Larubawa.
Olukọtan Anobi (SAW) Safiur -Rahman Mubarakfuriya ṣalaye ninu iwe rẹ pe, mọṣalaṣi yii yii lo tẹle ti Ka'baah.
Ati pe, ẹgbẹ ilé Anabi Muhammed (SAW) ni wọn kọkọ kọ mọṣalaṣi yii si ni Medina ki wọn to maa fẹẹ si bi ọpọ ero ṣe n wa sibẹ wa kirun lọdọọdun.
Bawo ni Mọṣalaṣi nla yii ṣe bẹrẹ?
Gẹgẹ bi Mubarakfuri ṣe sọ, Anabi ti ra oko paini mẹwaa lọwọ Sahl ati Suhail ti wọn jẹ awọn ọmọ orukọ meji ni kete to de Medina ni.
Anabi Muhammed (SAW) fọwọ sii pe ki ibẹ jẹ ibi adura lati maa kirun si Olorun Ọba.
Amọ ni wọn kọkọ fi mọ mọṣalaṣi yii pẹlu okuta.
Wọn fi imọ ọpẹ ati ẹpa rẹ ṣe orule sori ile ti wọn mọ naa lasiko yẹn.
Ilẹkun mẹta ni o ni ki wọn to pada si ariwa nigba ti A-Kibla ṣi lọ si Ka'bah ni eyi ti wọn fi ti ilẹkun guusu rẹ pa ti wọn n lo ti ariwa.
Iwọn ẹsẹ bata ẹgbẹrun kan ati aadọta ni o kọkọ jẹ nibẹrẹ ki wọn to sọọ di ẹgbẹrun kan ati aadọta le ni irinwo ẹsẹ bata.
Kete ti awọn anabi ṣí kuro ni Mecca wa si Medina ni wọn kọ mọṣalaṣi yii ni 632 AD.
Awọn eniyan gbagbọ pe adura kan ninu mọṣalaṣi yii niwọn to ẹgbẹrun kan ninu mọṣalaṣi miran yatọ si ti Ka'bah.
Iboji saare anabi Muhammed (SAW) ati ti Umar ati Abubakar ti wọn jọ n rin naa wa ninu mọṣalaṣi nla yii lẹyin ti wọn fẹẹ ni ọdun 1,400 sẹyin.
Iboji saare iyawo Anabi, Aisha naa wa nibi to jẹ iyara Anabi nigba kan ṣugbọn to ti wa ni ẹhinkule iwaju ibi ikirun lẹgbẹ kan bayii naa wa nibẹ.
Ibudo ti Anabi pe ni Royda to jẹ ibi isinmi alaafia bii paradise to wa laarin ile anabi ati mọṣalaṣi nigba aye rẹ ti wa ninu mọṣalaṣi yii bayii lẹyin ti wọn tun ti fẹẹ sii ko le gba ọpọ ero.
Odiwọn awọn nkan inu Mọṣalaṣi nla ni Medina:
Iwọn ẹsẹ bata mejidinlọgọrun un ni fifẹ ati ni ẹsẹ bata marundinlọgọfa ni gigun ni Zafar Bangash to kọ iwe itan anabi eyi ti Institute of Contemporary Islamic Thought gbe sita sọ.
Bayii, wọn tun ti fẹ mọṣalaṣi yii si ko le gba awọn to n wa ṣe Hajj lati gbogob agbaye.
Awọn eniyan ni o ti tobi ju ilọpo meji eyi lasiko yii.
Iboju awọn eekan ninu Islam nibẹrẹ wa ni Baq'i ni iwọ oorun mọṣalaṣi naa.
Lọdun 2012 ni Oba Abdullah gbe igbesẹ lati tun fẹ mọṣalaṣi yii sii.
Minista fun ọrọ owo nina ni Saudi Arabia, Ibrahim Assaf ṣalaye pe odiwọn mọṣalaṣi naa yoo to iwọn 614, 800 ẹsẹ bata ni eyi ti awọn agbegbe rẹ naa yoo to 1, 020, 500 ẹsẹ bata ni eyi ti yoo gba miliọnu kan awọn olujọsin o kere tan lẹẹkan ṣoṣo.
Ọpọlọpọ awọn nkan iranti ni wọn yoo ri si mọṣalaṣi naa ki awọn eniyan ma baa gbagbe orisun wọn ati awọn iṣẹlẹ inu Kurani.
Ipele aja keji ati aja kẹta mọṣalaṣi yii yoo gba to eeyan 800, 000 to ba maa fi di ọdun 20140 ninu erongba ijọba Saudi.
Bawo ni wọn ṣe n tọju Mọṣalaṣi yii?
Oba ilẹ Saudi Arabia lo n ṣakoso awọn mọṣalaṣi nla mejeeji to wa ni Mecca ati ni Medina.
Ijọba Saudi lo n ṣamojuto mọṣalaṣi wọn yii.
Egbẹlẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lo n ṣiṣẹ ninu mọṣalaṣi yii lojoojumọ.
Iru awọn oṣiṣẹ to wa ni Mọṣalaṣi Medina:
Awọn ẹṣọ alaabo ti wọn n ṣo mọṣalaṣi naa pọ diẹ yatọ si awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn mojuto iṣẹlẹ pajawiri lori ilera awọn eniyan.
Awọn panapana naa n ṣiṣẹ lọsan loru ninu mọṣalaṣi nla yii.
Yatọ si awọn Imaamu ti wọn n ṣaaju irun atawọn onimọ omiran ti wọn n danilẹkọọ ti wọn n ṣadura ninu mọṣalaṣi naa.

Oríṣun àwòrán, @others
Awọn eeyan miran tun fi ara wọn jin ti wọn n ṣiṣẹ laigbowo ọya nibẹ.
Abdulwahed Hatab to jẹ olori ẹka iṣẹ ode fun ori ade Saudi Arabia ni o kere tan, eniyan ẹgbẹrun meta lo n tọju mọṣalaṣi naa ati agbegbe rẹ.
Ile iwosan, ọọfiisi ijọba apapọ, ile itura, ile itaja igbalode, ati awọn opopona marosẹ lo wa ni ayika mọṣalaṣi nla naa.
Awọn Imaamu to ti ṣaaju irun ni mọṣalaṣi Medina:
Anabi Muhammed, (SAW) lo kọkọ kirun ni mọṣalaṣi Medina.
Oun lo n ṣaaju irun nibẹ titi to fi jalaisi ki awọn Imamu miran to maa ṣaaju irun.
Anabi Abubakar to jẹ ọrẹ tootọ fun ojiṣẹ nla naa ṣaaju irun nibẹ.
Ọpọlọpọ àwọn Imaamu lati Medina, lati Saudi Arabia ati lati awọn ilu miran lo ti ṣaaju irun ni mọṣalaṣi yii lẹyin iku anabi Muhammed (SAW).
Sheik Abdul Rahman Al-huthaifiy lo jẹ Imaamu agba lasiko yii yatọ si awọn imaamu marun un miran ti wọn jọ maa n pe irun nibẹ.
Lọjọ Jimoh, ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni ijọba Saudi tun yan imaamu meji tuntun Sheik Ahmed Hudaify ati Sheik Khalid AlMuhanna lati pẹlu wọn maa ṣaaju irun.

Oríṣun àwòrán, @others
Awọn imaamu miran ti wọn jẹ aṣaaju ẹsin nibẹ paapaa lasiko Tahajjud ni:
.Sheikh Abdulrahman Ali Hudhayfee
• Sheikh Abdul Bari Ath Thubaiti
• Sheikh Salaah Budai
• Sheikh Abdullah Buayjaan
• Sheikh Ahmad Al Hudhayfee
• Sheikh Ahmad Taleb Hameed
• Sheikh Hussain Aal Sheikh
• Sheikh Imaad Zuhair Hafiz
• Sheikh Khalid Al.

Oríṣun àwòrán, @others





















