Àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Iran ti lè wo bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá báyìí

Awọn obinrin Iran

Oríṣun àwòrán, @90min_Football

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ awọn obinrin Iran lo ti gbaradi loni lati foju ganni idije bọọlu fun igba akọkọ

Ọpọlọpọ orilẹ-ede agbaye ni ko fun awọn obinrin lanfani lati ṣe awọn ohun kan ti awọn okunrin lee ṣe.

Sugbọn lati ọdun diẹ sẹyin ni ayipada ti n de ba awọn ofin naa, ti awọn obinrin si ti n ni oreọfe lati dawọle awọn ohun naa bi wiwa ọkọ, kikopa ninu idibo, eti bẹbẹ lọ.

Eyi lo mu BBC wo awọn orilẹ-ede to fofin de awọn obinrin lori awọn ohun kan tẹlẹ, sugbọn ti wọn ti gba awọn obinrin laaye lati ṣe awọn ohun naa bayii.

1. Iran

Laipẹ yii ni awọn obinrin ni orilẹ-ede Iran yoo lanfani lati wo idije bọọlu alafẹsẹgba lori papa fun igba akọkọ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Idije naa ti wọn fi jaa loju waye laarin ikọ orilẹ-ede Iran ati Cambodia, ni papa iṣere Azadi, to wa ni Tehran,to jẹ fun igbaradi idije ife ẹyẹ agbaye to maa waye lọdun 2022.

Ọpọlọpọ awọn obinrin orilẹ-ede naa lo jade lati foju gan an ni idije ọhun nigba ti o waye ni Iran.

2. Saudi Arabia

Lati ọpoọlọpọ ọdun sẹyin ni obinrin Saudi ko ti lanfani lati wa ọkọ, sugbọn lati ọdun 2017 n i nnkan ti bẹrẹ si n yipada.

Ni bayii, awọn obinrin ni Saudi ti n wa ọkọ funra wọn, wọn si lee jade lọ si ibikibi lai si pe ọkọ wọn tele wọn lẹyin.

Bẹẹ naa ni obinrin tun lee kopa ninu idibo ati lati gbe apoti idibo, eyi ti ko ri bẹẹ tẹlẹri.

Àkọlé fídíò, Kini Yoru[bá ń pe Necklace?

Ko tan sibẹ, awọn obinrin ni Saudi ti lẹtọ labẹ ofin lati lọ wo sinima nile sinima, wọn tun ti le da okowo tiwọn silẹ lai lọwọ ọkọ wọn ninu.

Awọn obinrin Saudi lee ṣere idaraya ita gbangba bayi, wọn si tun ti lẹtọ labẹ ofin lati darapọ mọ ẹgbẹ ologun, eyi ti ko ribẹ tẹlẹri.

3. Rwanda

Tẹlẹri, orilẹ-ede Rwanda ko ka awọn obinrin si.

Sugbọn ni ọdun 2003 ni orilẹ-ede ọhun gba awọn obinrin laaye lati ni ida ọgbọn ijoko ni ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa.

Ni bayii, nnkan ti ṣẹnu ire fun awọn obinrin, nitori awọn lo ni aga ida ọgọta ni ile aṣofin kekere, ti wọn si ni aga to jẹ ida mejidinlogoji nile aṣofin agba orilẹ-ede ọhun.

4. Pakistan

Iku ni ere ẹnikẹni to ba ṣe ayipada lati akọ tabi abo si akọ lorilẹ-ede Pakistan tẹléri, sugbọn orilẹ-ede ọhun ti fun awọn irufẹ awọn eeyan bẹẹ lẹtọ labẹ ofin lọdun 2009.

Ni oṣu kẹrin ọdun yii ni ijọba Pakistan gba awọn to ba ti ṣe iyipada lati akọ si abo tabi abo si akọ lati le darapọ mọ ajọ ọlọpaa ilẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

5. Iceland

Lati ọdun 1961 ni orilẹ-ede Iceland ti n san owo oṣu to kere fun awọn obinrin, ti ko si ribẹ fun awọn okunrin.

Sugbọn ni ọdun 2018 ni ijọba orilẹ-ede ọhun yi ofin pada to si kan nipa fun awọn ileeṣẹ lati ma san iye owo kan fun takọtabo.

Ijọba ọhun ni, bẹrẹ lati ọdun 2022, ileeṣẹ ti ko ba tẹle ofin naa yoo fojuba ile ẹjọ.