Queen's College: Ohùn tó yẹ kí ẹ mọ nípa akọni Efunjoke Coker

Aworan Efunjoke Coke

Oríṣun àwòrán, Twitter/QcogaB

Àkọlé àwòrán, Pupọ awọn akẹkỌọ to kẹkọ labẹ Efunjoke Coker ni wọn wa nipo giga lawujọ Naijiria loni
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi Onirese ko ba fingba mọ, eleyi to ti fin silẹ ko ni parun layelaye.

Bayii ni ọrọ ri nigba ti a ba n woye itan olukọ agba ileewe girama awọn obinrin to wa nilu Eko nii, Queens College.

Iyaafin Efunjoke Coker ni olukọ agba akọkọ ileewe naa to jẹ ọmọ bibi Naijiria, koda ni ile ẹkọ naa ni oun gan an alara ti pari ẹkọ ki o to wa pada sibẹ lati dari ẹkọ.

Ọpọ awọn akẹkọọ lo sọrọ lori akọni obinrin yii.

Awọn ti wọn ti ni anfaani lati kẹkọọ jade labẹ akoso abiyamọ yi, ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii abiyamọ tootọ to mu iṣẹ olukọ lọkunkundun pupọ.

Wọn ni alakitiyan ni Mama Coker jẹ ti kii si fi ọrọ awọn ọmọbinrin ti wọn wa labẹ rẹ ṣere.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Lọdun 1979 ni ijọba Naijiria ṣafihan imoore iṣẹ ti Efunjoke Coker ṣe ati ipa to ko lori awọn akẹkọọ ileewe naa.

Wọn fi ami ẹyẹ Member of the Order of the Federal Republic (MFR ) da a lọla ti a si tun gbọ pe o gba oye to gaju lọ nibi ayẹyẹ idanimọ 2016 KARIS award.

Efunjoke Coke

Oríṣun àwòrán, Legit.ng

Àkọlé àwòrán, Efunjoke Coker ni obinrin ọmọ Naijiria akọkọ to jẹ ọga agba ileewe girama awọn obinrin Queens College.

Gẹgẹ bi ọrọ ti aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọjade ileewe Queens College, Dokita Funmi Ajose sọ,''awokọṣe rere ni iya Coker jẹ si awọn akẹk rẹ ti eyi si lapa ni igbesi aye wọn atiiṣẹ ti wọn yan laayo''

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lẹyin ti Efunjoke Coker fẹyinti nibi iṣẹ, o jẹ ọkan lara awọn Igbimọ alaṣẹ fasiti Ibadan ati ile iwe gbogboniṣe Yolanda Polythecnic.

Bakan naa lo ti ṣe aarẹ ajọ alagbelebu pupa, Red Cross fun ọpọlọpọ ọdun.