Kunle Olasope: Lekan Alabi ní onírẹ̀lẹ bíi àgbà àgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà sọ̀wọ́n

Oríṣun àwòrán, Others
Kìí ṣe ohun tuntun mọ pé ọkunrin akọkọ to farahan lori amohunmaworan, Kunle Olasope ti fí duniyan silẹ sùgbọ́n àwọn alábasisẹ́ pọ̀ rẹ nigba ayé rẹ tí n jẹri si ǹkan ti wọn mọ̀ọ nipa rẹ.
BBC Yoruba ba ọkàn nínú àwọn alábasiṣẹ́ pọ rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn sọ̀rọ̀, tii tun se Agba oye kan nilẹ Ibadan, Lekan Alabi sàlàye pé òun mọ baba náà fún ìgbà àkọkọ ní ọdún 1964, nígbà ti òun wà ní ọmọ ọdún mẹrinla.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àṣírí tú! Olùkọ́ fásitì méjì ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ fún máákì
- Wo ìdí to fi gbọdọ̀ yàgò fún Bobrisky, akọ tó ń ṣe bíi abo
- Músò! Músò! Músò! Mercy ló gbadé BBNaija ọdún 2019
- Àṣírí tú! Olùkọ́ fásitì méjì ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ fún máákì
- "Nína afurasí ní àhámọ́ nínú eré tíátà, bí àwọn ọlọ́pàá ti ń ṣe lójú ayé burú jáì"
Oloye Lekan Alabi ní àsìkò náà ni Olasope wa fún ìdánilẹkọọ nile iwe òun, sùgbọ́n isọrọ̀ si, ìrìn àti ìwọsọ bàbá naa lo jẹ ki òun bẹ̀rẹ̀ si ni fi èrò si láti yan iṣẹ́ iroyin láàyo.
Agbaoye Alabi fí kun pé, lẹ́yìn ti oun tún pari ilé iwé , ore-ofẹ́ tún yọ láti le jọ ṣiṣẹ́ papọ tí o si fún oun ni ànfani láti le kọ ẹkọ bi ènìyàn ṣe le ṣe iṣẹ́ ìròyìn bo ti tọ́ àti bi o ti yẹ.
O ní iṣẹ́ Olasope yii jọ mọ abini nítori pe, o mọ bi a tii se àgbékalẹ̀ ìròyìn, èyí ti kò wọ́pọ̀ mọ bayìí láàrin àwọn akọroyin, pàápàá julọ bi awọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kìí ṣe ni ìwé àkọsilẹ mọ, ki wọn to wọ yàrá ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́.
Alabi ni bo tilẹ jẹ́ pé kìí ṣe abẹ rẹ tààrà ni oun ti ṣiṣẹ̀, síbẹ̀, ìgbé aye Olasope jẹ ǹkan ti eniyan ń tẹ̀le, ṣe ni ti èdè ni tàbí làákàyé? o tẹramọsẹ, kìí si se ọ̀lẹ̀.
"Eyi to ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, Ọtunba Kunle Olasope kìí korira ẹnikẹni, kìí ṣe ìgbéraga tàbi ko ma foju pa ẹnikẹni rẹ.
Bí Kunle Ọlasọpe, ìlúmọ̀ọ́ká agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ rèé
Awaye ku ko si, ọrun ma kanju, gbogbo wa la n bọ.
Oloogbe Kunle Ọlasọpe, tii se ọkunrin akọkọ to fi oju han lori mohunmaworan ti waye, to si ti lọ, amọ o yẹ ka ran ara wa leti nipa awọn ohun ribiribi to gbe ile aye se.
Ọjọ Aiku, ọjọ Kẹfa, Osu Kẹwa, ọdun 2019 ni gbajugbaja agbohunsafẹfẹnaa, Kunle Olasope jade laye lẹni ọgọrin ọdun amọ bi onirese rẹ ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ko yẹ ko parun.
Kunle Olasope ní ifẹ si isẹ iroyin lo jẹ ko lọ si ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC lati lọ gba imọ kun imọ nipa isẹ igbohunsafẹfẹ lọdun 1962.
Gẹgẹ bi itan igbe aye rẹ ti sọ fun wa lori ayelujara, baba to bi baba Olasope ni iyawo mẹwa, ti iya tirẹ si jẹ iyawo keji, ti oun naa si jẹ ọmọ kẹfa ninu ọmọ mẹrindinlọgbọn.

Oríṣun àwòrán, Others
Ifẹ rẹ fun iroyin lo jẹ ko lọ si ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC lati lọ gba imọ kun imọ nipa isẹ igbohunsafẹfẹ lọdun 1962.
Nkan to yẹ ko o mọ nipa Baba Kunle Olasope:
- Ọmọ bibi ilu Ẹfọn Alaaye nipinlẹ Ekiti ni Kunle Ọlasọpe, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Julius Ọlasọpe
- Ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn bi Olasope si ni Ọjọ Kẹjọ, Osu Karun un, ọdun 1937 ladugbo Oke Padi
- Olasope lọ si ile iwe alakọbẹrẹ Agbeni Methodist ni ilu Ibadan, ti o si wọle si ile iwe girama Igbobi, ni Yaba ni ilu Eko lọdun 1951
- Bakan naa lo jẹ́ olori awọn akẹkọ nile ẹkọ girama naa, ko to kẹkọ jade
- Fun eto ẹkọ fasiti, Olasope lọ si ibudo ẹkọ irọlẹ tii se ẹka ileẹkọ fasiti Ile Ife to kalẹ silu Ibadan
- Nigba ti ẹrọ amọhunmaworan de si Naijiria lọdun 1959, Kunle Olasope pẹlu Anike Agbaje-Williams ati John Edyang ni wọn bẹrẹ ikede ni ile isẹ mohunmaworan WNTV, tii se akọkọ nilẹ Afirika
- Gẹgẹ bi ẹni akọkọ to ka Iwe lroyin lori ẹrọ amohunmaworan, Olasope kopa ninu bi ile isẹ iroyin naa se gbe afihan asa ilẹ wa, taa mọ si FESTAC 77 si ori afẹfẹ jakejado Naijiria
- Kunle Olasopegba ọpọ ami ẹyẹ, diẹ lara rẹ ni ami ẹyẹ Naijiria (MON) lọdun 2000, tijọba ipinlẹ Ekiti naa si fi ami ẹyẹ daa lọla lọdun 2004
- Olasọpe, nigba aye rẹ ma n parọwa si awọn ọdọ lati jara mọ isẹ ti wọn n se, ki wọn si yago fun wiwa owo ojiji
- Nigba to jẹ pe ile ni abọ sinmi oko, Kunle Olasope ko lọ silu Ẹfọn Alaaye lẹyin to fẹyinti lẹnu isẹ, to si n kopa lọkan o jọkan si idagbasoke ilu naa
- Olasope ni iyawo, to si bi ọpọ ọmọ ki iku to pa oju rẹ de lẹni ọdun mejilelọgọrin ọdun.












