Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́
Yoruba ni ẹsin kii jẹ koriko abẹ rẹ amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn olukọ fasiti meji kan to n beere fun ibalopọ lọwọ akẹkọ.
Fọnran aworan yii, lo je ifinmu finlẹ ikọ ọfintoto BBC Africa Eye ni fasiti meji lẹkun iwọ oorun Afirika, eyiun fasiti Eko taa mọ si UNILAG ati fasiti Ghana.
Fọnran yii si lo n se afihan awọn olukọ fasiti meji lawọn ileẹkọ mejeeji yii ti wọn n beere ibalopọ lọwọ awọn akẹkọ to fẹ wọle sọgba ile ẹkọ wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fásitì Ghana lé olùkọ́ méjì tí àṣírí wọ́n tú lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ lọlé
- Àpọ̀jù òògùn ikọ́ olómi Codeine, ìbẹ̀rẹ̀ wèrè
- Ọ̀rọ̀ ń bọ́ lóríi fídíò Codeine
- 'Kìí ṣe àròsọ, mo ní fọ́nrán fídíò àwọn ẹlẹyẹ ìlú mi'
- Bí ìròyìn BBC nípa oògùn ikọ́ Codeine ṣe ń tún ayé tó ti bàjẹ́ ṣe
- Ìwádìí fídíò ayélujára tú àṣìrì ìpànìyàn Boko Haram
Koda, awọn akẹkọjade kan lawọn ileẹks naa tun salaye ohun ti oju wọn ati ti awọn akẹẹgbẹ wọn kan ti ri lọwọ awọn olukọ to kundun ibalopọ naa.
Ẹ wa nkan fidi le lati wo ẹkunrẹrẹ fidio naa, amọ o seese ki ara ta yin gẹgẹ bii abiamọ abi akẹkọ.