Africa Eye: Mo máá ń ṣàìsàn tí mi ò bá ṣiṣẹ́ òru
Ẹka ile iṣẹ BBC to n ṣe eto to maa n tu aṣiri awọn ohun to farasin, Africa Eye balẹ si ilu Luo ni orilẹede Kenya.
Ni ilu yii,gbogbo igba ni wọn maa n ni iriri abami loru ti wọn yoo kan maa gbọ ohun to n dẹru ba ni nita ile wọn ti ibẹrun bojo yoo si de ba wọn ninu ile.
Akọroyin Tom Odula bọ si gbogbo adugbo ilu ṣewadii boya lootọ, ẹmi okunkun lo n gbenu awọn to n ṣe iṣẹ abami yii loru ọganjọ.