Unicycle School: Olùdarí ibùdó ìkẹ́kọ̀ kẹ̀kẹ́ alájọwà ń fẹ́ ìrànwọ́ ìjọba
Nigba ti ọlaju kọkọ de silẹ Yoruba, kẹkẹ ologeere lo gbajumọ ti awọn eeyan si mọ dunju, amọ lode oni yii, ilana kẹkẹ wiwa kan tun ti de, eyi to n mu owo wa fun ni.
Kẹkẹ alajọwa ni wọn n pe, eyi to jẹ itẹwọgba bayii laarin awọn ọdọ, ti wọn fi n da awọn eeyan kanka laujọ lọla, koda, ileẹkọ nipa rẹ gan ti wa.
Nigba to n sọrọ lori agbekalẹ ibudo ikẹkọ kẹkẹ naa fun BBC Yoruba, Lekan Kuyoro tii se oludari ibudo naa ni, bii ere, bii ere lawọn n fi kẹkẹ sere nigba to bẹrẹ, ti awọn ko si mọ rara pe ọjọ iwaju rere yoo wa fun ere naa.
O ni o ti di itẹwọgba bayii nitori ko wọpọ laarin awọn eeyan dudu tẹlẹ, to si wa n beere iranwọ ijọba fun ipese ibudo ti awọn yoo ti maa se idanilẹkọ nitori ibi ti awọn wa bayii ko ni aabo to.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dòkítà tó ṣe iṣẹ́ abẹ fún oyún inú l‘Amẹrika ló ń sọ Yorùbá yìí, bíi ẹní la oyin
- Àrà méèrírí! Ọkùnrin tí kò ríran kan rèé tó ń lọ ẹ̀rọ ata
- Ìpanu ‘Cheese ball’ ni wọ́n fi jí Ikimot gbé, àmọ́ ó padà sílé lẹ́yìn ọdún márùn-ún
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- 5:30 p.m ni ojú mi déédé fọ́ níbi tí mo ti ń darí ọkọ̀ ni Ọrẹgun Ikẹja -LASTMA Yesufa
Lasiko abẹwo BBC sibi idanilẹkọ awọn ọdọ to n se kẹkẹ alajọwa naa, a ri ti wọn n fi kẹkẹ rin lori igo ti wọn to silẹ, eyi to wu ni lori.
Ẹyin naa ẹ wo fidio yi, ori yin yoo wu pupọ nipa awọn ọdọ naa.