Coronavirus cure: Olùdásílẹ̀ Yemkem ní ''Olóde'' ni Yorùbá ń pe coronavirus, iléeṣẹ́ Yemkem ti rí òògùn rẹ̀ báyìí

Akintunde Ishola Ayeni

Oríṣun àwòrán, Facebook/Yemkem Int'l

Ileeṣẹ Yemkem International to n fi ewe ati egbo ṣe oogun ati itọju awọn eeyan ti sọ pe awọn ti po ewe ati egbo pọ lati wo aarun coronavirus to n ba gbogbo aye finra lọwọ yii.

Oludasilẹ ileeṣẹ Yemkem International, Akintunde Iṣhola Ayeni to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn ti fi ewe ati egbo tọju awọn alaarun covid-19 kan ti wọn si ti gbadun.

Ọgbẹni Ayeni ṣalaye pe ''olode'' lawọn baba wa laye ọjọun maa n pe coronavirus.

O ni ohun ti wọn fi n pe ni olode ni pe aarun naa maa n gba ode lọwọ olode ni, ko ni jẹ ki oloko lọ soko, ko si ni jẹ ki olodo lọ sodo mọ.

Amọ oludasilẹ ileeṣẹ Yemkem ni ewe ati egbi ni Yoruba fi maa n tọju aarun naa laye igba kan.

Ọgbẹni Ayẹni sọ pe ọrọ covid-19 dabi ọmọ tuntun ti kii ṣe akọpa ajẹ fun ileeṣẹ Yemkem.

O ṣalaye pe ileeṣẹ Yemkem n ṣiṣẹ lori ṣiṣe oogun coronavirus ni koro ati olomi, laipẹ yii ni ileeṣẹ naa yoo fi ṣọwọ si ajọ NAFDAC fun ayẹwo.

Ọgbẹni Ayeni sọ pe awọn nilo ki ajọ NAFDAC fun oogun naa ni nọmba ki awọn to le bẹrẹ si ni taa, bi bẹẹ kọ, oogun naa ko le di tita lori igba.

Ẹwẹ, oludasilẹ ileeṣẹ Yemkem bu ẹnu atẹ bi Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu lilo agbo ti orilẹ-ede Madagascar ṣe fun itọju aarun covid-19.

O ni itiju nla ni ki orilẹede Naijiria maa lọ si orilẹ-ede kekere bi Madagascar fun iwosan aarun coronavirus nigba ti awọn elegbo igi wa ni Naijiria.

O ni ijọba ko gbaruku ti awọn to n fi ewe ati egbo ṣe ọmọ araye loore.