Coronavirus Cases in Africa: Gomina Makinde gbàlejò àwọn Imam lásìkò àrùn Coronavirus

OYO

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ àwọn Imam, the Joint Action Committee for the Preservation of the Rights and Honours of Imams tako àyẹyẹ naa.

Ọpọlọpọ awuyewuye ti tẹle igbesẹ Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde to pe awọn imaamu ni ipinlẹ Ọyọ fun ayẹyẹ Iftar.

Irọlẹ Ọjọru ni ayẹyẹ Iftar naa pẹlu awọn Alfa ati Imaamu waye ni Ile Ijọba Ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti Adari ikọ Iroyin Gomina Seyi Makinde, Taiwo Adisa fi lede fihan pe kii ṣe igba akọkọ ni yii ti gomina naa n ṣe ayẹyẹ yii.

Adisa fikun wi pe o da oun loju wi pe ayẹyẹ ohun koni tako ofin yiyagofunraẹni ati wi pe ti awọn eniyan naa ba pọju mẹwa lọ, awọn yoo wa n kan ṣe si.

Amọ awọn Ẹgbẹ́ àwọn Imam, the Joint Action Committee for the Preservation of the Rights and Honours of Imams tako àyẹyẹ naa.

Adari ẹgbẹ awọn Imaamu naa, Abu Muhammad ni Gomina naa takọ ofin ijọba apapọ lori yiyago funraẹni ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati koju itankalẹ arun Coronavirus to n ja rain lorilẹede Naijiria.

Abu Muhammad si kesi awọn imaamu ati Alfa ti gomina naa pe wi pe ki wọn ma da gomina naa lohun lasiko yii fun anfaani ara wọn.

Kí ni ìdí tí Àmọ̀tẹ́kùn kò tìí fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀?

Oludari agba fun ajọ iṣakoso okoowo ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria, DAWN, Ṣẹyẹ Oyelẹyẹ ti jẹ ko di mimọ pe ikọ alaabo ẹkun naa ti ọpọ mọ si Amọtẹkun ko ku o, bẹẹni ina rẹ ko parun.

Ọkọ ikọ amọtẹkun kan

Oríṣun àwòrán, osun state government

Ọgbẹni Ṣẹyẹ Oyelẹyẹ ṣalaye pe ko sohun meji to n da ibẹrẹ iṣẹ iks naa duro lawọn ipinlẹ ju wahala ajakalẹ arun coronavirus to gba aye kan bayii.

O fi kun un pe ko si ipinlẹ kọkan lara awọn ipinlẹ to wa lẹkun naa to pẹlyinda si afẹnuko lori idasilẹ ikọ ọhun.

Amọtẹkun jẹ ọkan lara awọn eto ti awọn ijọba ipinlẹ lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria gbe kalẹ lati koju oniruuru ipenija ọrs to n doju kọ awọn eeyan nibẹ.

Ọkanojọkan ifojusọna lawọn eeyan si ti ni lori ohun ti yoo tẹyin rẹ jade paapaajulọ pẹlu mọhurumọhuru awọn fulani darandaran kan lẹkun naa.

Awọn ọkọ ikọ Amọtẹkun ni igboro

Oríṣun àwòrán, osun state government

Amọṣa lẹyin ti ọrọ ikọ naa ho ṣukuṣuku fun igba diẹ lo ba da wai, eleyi to ti nkọ ọpọ lominu pe ṣe kii ṣe pe ohun naa, gẹgẹ bi ọpọlọpọ eto ijọba miran ti fori ks igbo.

Nibayii naa, ipinlẹ meji lo ti gbe igbimọ isakoso kalẹ fun ikọ naa ni ipinlẹ koowa wọn.

Ipinlẹ Ọṣun ati Ekiti ti gbe igbimọ kalẹ gẹgẹ bi itẹsiwaju igbesẹlẹyin ti gbogbo awọn ipinlẹ naa ti kọkọ buwọlu ofin Amọtẹkun ki wahala ajakalẹ arun coronavirus to wọle de