Osinbajo: Nasir El-Rufai ní igbákejì ààrẹ, Yemi Osinbajo ni alága àwọn 'kògajùgò' lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Governor kaduna
Ṣe ẹ mọ pe ai pepade awọn otoṣi ni ko jẹ ka mọ alaga iṣẹ? Aipepade awọn ti ko ga pupọ ni iduro ni ko jẹ ka mọ alaga awọn arara.
Eyi lọrọ to jẹyọ ninu apara kan ti gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai fi igbakeji aarẹ, Yẹmi Oṣinbajọ da pe oun ni alaga ẹgbẹ awọn eeyan ti ko ga pupọ lorilẹede Naijiria.
- Ìgbéyàwó èmi àti Aláàfin kò pé, ṣùgbọ́n...-Olorì Aláàfin, Memunat Adeyemi
- Àjọ NCDC kéde èèyàn 242 míràn tó ni ààrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Naijíríà
- Buhari pàṣẹ lílo àgbo tí orílẹ̀-èdè Madagascar ṣe fún coronavirus fún ìtọ́jú ọmọ Nàìjíríà
- Kókó ohun tó wà nínú àbọ̀ ìwádìí Orosanye, tó le gba iṣẹ́ lọ́wọ́ òṣìṣẹ́
Ni ọjọ Aje ni Gomina El-Rufai fi ọrọ yii sita loju opo twitter rẹ ni idahun si fidio kan eleyi ti gbajugbaja adẹrinpoṣonu ni, Tẹju babayface fi sita loju opo twitter nibi to ti n fi ọrọ wa El-Rufai lẹnu wo lọdun 2010 ti o si ni oun ni akọwe ẹgbẹ awọn eeyan kukuru lorilẹede Naijiria.
"Bẹẹni...Mo ranti ifọrọwanilẹnuwo @Tejubabyfacetv yii lọdun 2010...ọjọ ree bi ana...igbakeji aarẹ Osinbajo ni alaga awọn eeyan kukuru lọwọ yii..."

Nigerians Evacuated from UK: Ọgọ́jọ ọmọ Nàìjíríà tí coronavirus ṣé mọ́ Amẹrika ti gúnlẹ̀ s'Abuja

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerians in diaspora
Ọgọjọ ọmọ Naijiria ti coronavirus ṣe mọ ilẹ Amẹrika ti gunlẹ silu Abuja lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa oṣu karun un, ọdun 2020.
Aago mọkanla aarọ ọjọ Aiku ni baalu to gbe wọn lati New Jersey balẹ si olu-ilu Naijiria, Abuja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama kede loju opo Twitter rẹ pe wọn ti gunlẹ lalaafia l'Abuja.
Awọn mejilelaadọrun un ninu wọn lo jẹ ọkunrin nigba ti ọgọta jẹ obinrin, ọmọde lawọn mẹjọ to ku.
Ẹwẹ, ọkọ akero mẹfa lo ti wa nilẹ lati ko awọn eeyan naa lọ si ibudo iyasọtọ nibi ti wọn yoo wa fun ọjọ mẹrinla aibaamọ aarun coronavirus le wa lara wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ajọ to n ri ri irina ni yoo fi iwe irina awọn eeyan pamọ titi digba ti ọjọ mẹrinla naa yoo fi tan.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerians in Diaspora Comm
Ni nnkan bi ọjọ meji sẹyin ni ọta le lugba ọmọ Naijiria o din meje balẹ si Naijiria lati ilẹ Gẹẹsi.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti UK ti dèrò ibùdó ìyàsọ́tọ̀ nítori Coronavirus
Ijọba ti ko awọn ọmọ Naijiria 253 to pada sile lọjọ Ẹti lati ilẹ Geẹṣi lọ si ibudo iyatọ aibaamọ awọn mii ninu wọn le laarun coronaviris.
Isọri keji awọn ọmọ Naijiria to de lati ilẹ Gẹeṣi balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed (MMIA), niluu Eko
Ṣaaju ni awọn mii ti rinrin ajo wale lati Dubai lorilẹede United Arab Emirates (UAE)
Lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo bi ara wọn ṣe n gbona si ni wọn fi ọkọ ko wọn lọ si ibudo iyatọ ti wọn ti pese silẹ fun wọn.
Ọpọ ninu wọn ni wọn tun fi baalu gbe lọ si ilu Abuja nibi ti wọn yoo ti wa ni igbele fun ọjọ mẹrinla.

Ṣugbọn awọn kan wọn fi aidunnu wọn si bi wọn ti gbe wọn lọ si Abuja, wọn ni awọn ko lara tabi iyekan niluu Abuja.
Ìjọba kó àwọn ìpele arìnrìnàjò míràn dé láti UK nítori ààrùn Coronavirus
Lánàá odé yii ni ìjọba ko àwọn ipele arìnrìnajò míràn dé láti ilẹ̀ gẹ̀ẹ̀sí.
Ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni wọ́n ko àwọn kan de láti ìlú Dubai nítori ààrùn Coronavirus.
A mọ sá, ọ̀kan nínú àwọn arìnrìnajò láti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì to ba BBC Yoruba sàlàyé pe bi ìjọba ṣe n ṣe awọn ko bá ojúmu rárá.
Lásìkò to n ba BBC sọ̀rọ̀ Ọmọlabakẹ sàlàye pé ìdá ààdọrun nínú àwọn arìnrìn ajo ló jẹ́ olugbé ìlú Eko sùgbọ́n ìjọb a ni ilú Abuja ni àwọn yóò ti lọ já wọ́n silẹ̀.
O ní kò si oore kankan ti ìjọba ṣe fún ara ilú, nítori pé olúkúlúkù lo fi owó ara rẹ san owó ọkọ to fi wálé àti pé wọ́n ti sọ fún àwọn pé, ki olorí di ori rẹ̀ mú ni ti àwọn ba de ilú Abuja.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wọ̀ gàù l'Eko
Coronavirus returnees: Àwọn àbọ̀dé ọmọ Nàìjíríà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní òbítíbitì owó làwọn san ṣùgbọ́n ẹ̀gbin níjọba ń fojú wọn rí

Nnkan o rọgbọ fun awsn ọms Naijiria ti ijọba apapọ ko de lati orilẹ€de Gẹẹsi ni ọjọ Ẹti pẹlu bi gbogbo wọn ṣe n pariwo pe nṣe ni ijọba apapọ ru wọn da silẹ ni yanrin ikọle ni papakọ ofurufu ilu Eko.
Ohun ti ọpọ awọn abọde ilẹ Gẹẹsi naa n sọ ni pe lati nnkan wakati mẹta ti wọn ti de si papakọ ofurufu naa ni awọn ko ti ri ẹnikẹni ti yoo yọju siwọn lati sọ igbesẹ to kan.
Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ ti jẹ ko di mimọ pe ilu Abuja ni wọn yoo ko awọn eeyan wọnyii lọ, pupọ ninu wọn lo n faake kọri pe awọn ko mọ ẹnikẹni nilu Abuja ti awsn lee duro ti lẹyin ọjọ mẹrinla ti eto iyasọtọ kan n pa ti wọn fẹ fi wọn si ba pari.

Ohun ti wọn sọ ni pe ida aadọrun ninu awọn lo n gbe ni ilu Eko ti ko si si idi fun ijọba lati maa ru awọn lọ si ilu Abuja.

Ọkan lara awsn arinrinajo naa to ba BBC News Yoruba sọrọ to pe ara rẹ ni Labakẹ ṣalaye pe pupọ ohun ti awọn alaṣẹ n fi oju awọn ri ni ko kun oju iwọn ati pe wọn ko ro tiwọn rara ninu eto wọn.
Ni ọsan ọjọ Ẹti ni baaluu ilẹ Gẹẹsi ko igba o le aadọrin awọn ọmọ Naijiria kan pada si orilẹede Naijiria.
Wakati mẹrin lẹyin ti awọn eeyan wọnyii gunlẹ ni ko si ẹnikẹni ti yoo yọju si wọn.
Iṣi akọkọ awọn ọmọ Naijiria to ha si ilẹ Gẹẹsi naa gunlẹ si papakọ ofurufu muritala mohammed ni ilu Eko lọsan ọjọ Ẹti.
Arabinrin Dabiri-Erewa ni ilu Eko lawọn eeyan naa yoo maa gba lọ silu Abuja taarata nibi ti wọn yoo ti fi wọn si igbele ọjọ mẹrinla lati mọ boya wọn laarun coronavirus tabi wọn ko ni.

Ni ọjọru ni iṣi akọkọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria to ha si orilẹede UAE pada de lati ilu Dubai ti wọn si ti fi wọn si ahamọ.
Coronavirus: Pé wọ́n bi ọ sínú bàálù orílẹ̀-èdè kan kò túmọ̀ sí pé ó ó di ọmọ ibẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ orilẹ-ede ti ọmọ ti wọn ba bi sinu baalu tabi ọkọ oju omi yoo jẹ kii ṣe oni lo bẹrẹ.
O si jẹ ọkan pataki lara ofin to wa ninu iwe ofin ajọ iṣọkan agbaye, ṣugbọn iha ati ilana ti orilẹ-ede kọọkan n ṣamulo yatọ lori orilẹ-ede ti ọmọ naa yoo maa jẹ.
Labẹ abala kẹtadinlogun si ikọkanlelogun ofin lori ọrọ irinajo oju ofurufu lagbaye lọdun 1944, gbogbo ileeṣẹ baalu lo ni orilẹ-ede to forukọ silẹ si, to si le ma ju ẹyọkan lọ, ofin orilẹ-ede naa lo si de ileeṣẹ ọkọ ofurufu naaa. Ṣugbọn ṣa, orilẹ-ede kọọkan lo ni aṣẹ lati sọ ẹni to jẹ ọmọ orilẹ-ede rẹ.
Nitori naa, ofin yii ko sọ pe wọn gbọdọ ri ọmọ ti wọn bi sinu baalu orilẹ-ede kan, gẹgẹ bi pe orilẹ-ede naa ni wọn bi i si nitori a ti di ọmọ oniluu.
Ṣugbọn ṣa, abala kẹta ofin ti awọn orilẹ-ede fẹnuko le lori lọdun 1961 lori iru ọrọ yii labẹ akoso ajọ to n mojuto ọrọ awọn atipo l'agbaye, UNHRC, sọ pe ọmọ ti wọn ba bi loju ofurufu tabi ori omi ti orilẹ-ede agbaye, ni wọn yoo gba gẹgẹ bi i pe orilẹ-ede ti baalu tabi ọkọ oju omi naa forukọ silẹ si ni wọn bi i si.
Ṣugbọn o, ofin yii kii ṣaba jẹ mimulo, nitori pe ọmọ tuntun ti ni orilẹ-ede abinibi tẹlẹ (ibi ti awọn obi rẹ ti wa).
Bẹ ẹ si ni kii ṣe gbogbo orilẹ-ede lo ṣi faramọ ofin ọdun 1961 ọhun.
Ajọ to n mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijria nilẹ okeere ti ko awọn ọmọ Naijiria to ha si ilu Dubai pada sile.
Alẹ ọjọru ni awọn eniyan ọtalenigba din mẹẹrin (256) naa de pada si Naijiria.
Ninu ikede to fi sita, ajọ naa sọ pe gbogbo wọn ni ayẹwo fihan pe ko ni coronavirus lara, ṣugbọn wọn yoo ko wọn si ibi kan fun iyasọtọ tipatipa fun ọjọ mẹrinla.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ọsan ọjọru lo yẹ ki wọn o gunlẹ si Naijiria, ṣugbọn obinrin alaboyun kan to jẹ ara wọn bimọ sinu baalu, eyi to mu ki wọn o ni idaduro diẹ.
Ninu atẹjade kan ti Abdurahaman Balogun fi sita lorukọ ileesẹ NIDCOM, Arabirin Kafayat Amusan bi ọmọ ọkunrin lantilanti sinu baalu ileesẹ Emirate to n bọ wa si Eko lati Dubai.
O sọ pe ni nkan bi ọgbọn isẹju ti baalu gbera lo fẹsẹ tẹlẹ ti o si sọ layo.
Ewẹ o ti wa ni ile iwosan kan ni Dubai to ti n gba itọju ti iya ati ọmọ tuntun naa si wa lalaafia.
Abike Dabiri Erewa to jẹ ọga agba NIDCOM sọ pe kete ti wọn ba ti gba iwe ẹri ibi ati awọn iwe mii fun ọmọ naa,oun ati iya rẹ yoo pada wa sile.

















